Ilé ìwé tuntun kò wúlò mọ́ fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ ìpínlẹ̀ Kogi

Image copyright @Dino
Àkọlé àwòrán Awọn janduku ba ẹ̀tọ́ àwọn akẹkọọ ipinlẹ Kogi jẹ́

Àwọn kan ti dáná sun iṣẹ́ àkànṣe Dino nilé ìwé Government Girls Secondary School ni Lokoja.

Lọjọ Ru ni àwọn afurasi Janduku kan lọ dana sun awọn iṣẹ akanṣe ti Senetọ Dino Melaye lati iwọ oorun ipinlẹ Kogi fẹ ṣí laipẹ.

Ile iwe awọn akẹkọbinrin ti agbegbe Sarkin-Noma ni Lokoja atile iwe alakọbẹrẹ ti LGEA ni Lokogoma ni wọn ti bajẹ.

Image copyright @Dino
Àkọlé àwòrán ọjọ ọla awọn akekoo kan ni janduku ti dana sun ni Kogi

Awọn eniyan ipinle Kogi ati gomina ipinlẹ Kogi ti benu ẹ̀tẹ́ lu iwa bàsèjẹ́ yii pé dié lara èrè iṣejọba awa-ara-wa to yẹ ki awọn akẹkọọ jẹ ni awọn janduku yii ti bajẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Inu Senetọ Dino Melaye to n ṣoju ijọba ibilẹ meje ni iwọ oorun Kogi ko dùn rara si ohun to ṣẹlẹ yii.

Iṣẹlẹ náà ni àwọn kan gba pe kò ṣẹ̀yìn gomina Yaya Bello to n tukọ ipinlẹ Kogi pe

Ọpọlọpọ gba pe iṣẹlẹ yii jẹ́ ẹ̀rù ohun ti oṣelu Naijiria ti di bayii pẹlu ifoya ọkan lori ọjọ iwaju ijọba tiwantiwa ni Naijiria

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionRussia 2018: Awọn alátilẹyin àgbabọọlu kò le pada sílé
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKhadijat Oluboyo: Ilé ẹjọ́ sọ ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ sí gbaga