Judith okey: Awakọ̀ ẹ̀gbọ́n mi sẹ̀sẹ̀ gbéyàwó ni láì bímọ

Judith okey: Awakọ̀ ẹ̀gbọ́n mi sẹ̀sẹ̀ gbéyàwó ni láì bímọ

Aburo arabinrin Marie Okey, Judith, ti ké gbàjarè tọ BBC Yorùbá wá pé òun kò mọ́ bóyá ẹ̀gbọ́n òun kú tàbí yè nínú ìsẹ̀lẹ̀ ọkọ̀ epo tó gbiná ní àdúgbò Ọ̀tẹ̀dọlá, ní ìlú Èkó láìpẹ́ yìí.

Ó ní àwọn ń wá awakọ̀ tó gbé ẹ̀gbọ́n òun pẹ̀lú, ẹni tó sẹ̀sẹ̀ gbéyàwó láì tíì bímọ.

Judity wá ń rọ ìjọba láti fààyè gba ẹbí àwọn èèyàn tó forí sọta ìsẹ̀lẹ̀ iná náà, láti wọ ibùdó ìtọ́jú aláìsàn tó gbẹlẹgẹ́ (Intensive care) tí wọ́n gbé àwọn èèyàn náà sí, bóyá ẹ̀gbọ́n òun leè wà lára wọn.