Òsìsẹ́-fẹ̀yìntì Èkìtì ké pe Fáyẹmí kó má gbàgbé àdéhùn
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Òsìsẹ́-fẹ̀yìntì Èkìtì: À ń bẹ̀bẹ̀ fún gómìnà tí yóò sàánú wa

Alága ẹgbẹ́ òsìsẹ́-fẹ̀yìntì Èkìtì, Ayọ̀ Kúmápàyí ti késí gómìnà tí wọ́n sẹ̀sẹ̀ dìbò yàn ní ìpínlẹ̀ Èkìtì, Ọ̀mọ̀wé Káyọ̀dé Fáyẹmí láti máse kẹ̀yìn sí àdéhùn tó se láti san àjẹsílẹ̀ owó ìfẹ̀yìntì wọn.

Lásìkò tó ń bá BBC Yorùbá sọ̀rọ̀, Kúmápàyí ní láti ọdún 2012 ni òwó ìfẹ̀yìntì òsìsẹ́ ti ń wọ́lẹ̀.

Ó ní àwọn ti gbàdúrà sáájú pé kí Ọlọ́run yan gómìnà aláànúú fún ìpínlẹ̀ Èkìtì.