Osun Election: Èrò àwọn olùdíje yapa lórí ìbò abẹ́nú APC

Awọn ọmọ ẹgbẹ oselu APC Ọsun
Àkọlé àwòrán,

Awọ̀n oludije fun ipo gomina ninu ẹgbẹ APC nipinlẹ Ọ̀sun ko lee fẹnu ọrọ jona lori awọn ilana kan to nii se pẹlu eto idibo ọ̀hun.

Ẹ̀kọ ko soju mimu nilu Osogbo lọjọbọ nibi ipade awọn alẹnu-lọrọ̀ fẹgbẹ APC ni ipinlẹ Ọ̀sun to waye lana eyiti igbimọ to n se kokari ibo abẹnu naa se kokari rẹ.

Idi ni pe awọ̀n oludije fun ipo gomina ninu ẹgbẹ APC nipinlẹ Ọ̀sun ati igbimọ to n se kokari eto idibo abẹnu naa, ko lee fẹnu ọrọ jona lori awọn ilana kan to nii se pẹlu eto idibo ọ̀hun.

Àkọlé fídíò,

Àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú APC nipinlẹ Osun n ṣe ìpàdé

Alaga igbimọ to n se kokari eto idibo abẹnu naa, tii tun se gomina ipinlẹ Zamfara, Abdulaziz Yari, ẹ́niti Sẹnetọ Ọmọ Agege soju fun, pe ipade naa lati fi eegun otolo to awọn gbọn mi si-omi o to kan to n waye ninu ẹgbẹ oselu naa ni.

Akọroyin BBC Yoruba to wa nilu Osogbo nibi ti ipade naa ti waye ni, o dabi ẹni pe gbun-gbun-gbun naa ko lee niyanju nitori pe o ti foju han lati ibẹrẹ ipade naa pe, iyapa lee ba awọn ọmọ ẹgbẹ oselu naa nitori bi awọn alatilẹyin awọn oludije se n kọrin eebu, ti wọn si n yẹyẹ ara wọn, lati sọ ibi ti wọn fi si.

Àkọlé àwòrán,

O dabi ẹni pe gbun-gbun-gbun naa ko lee niyanju nitori pe o ti foju han lati ibẹrẹ ipade naa pe, iyapa lee wa

Wahala lo gba inu ẹgbẹ oselu APC Ọsun kan nitori ilana idibo lawọn ijọba ibilẹ ti ẹgbẹ naa fẹ lo lati yan ẹniti yoo soju APC nipinlẹ Ọsun ninu idibo gomina to n bọ.

Ti a kò bá gbàgbé, ẹgbẹ òṣèlú APC ti sáájú kéde isunsiwaju ọjọ ìdìbò lati yan olùdíje ẹgbẹ fún ìbò Gómìnà nipinle Osun, lati Ọjọbọ si ọjọ Ẹti.

Èèyàn mẹtadinlogun ló n dije láti gbé àsìá ẹgbẹ APC sókè bíi olùdíje gómìnà ní ìpínlẹ̀ Osun.

Àkọlé àwòrán,

Èèyàn mẹtadinlogun ló n dije láti gbé àsìá ẹgbẹ APC sókè bíi olùdíje gómìnà ní ìpínlẹ̀ Osun.

Nigba ti ipade alaafia ti wọn pe lana wa fori sanpọn, n jẹ bawo ni eto abẹnu lati yan oludije fun ipo gomina ti yoo waye loni yoo se lọ ?

Ẹ maa ba wa bọ lori ikanni yii lati maa fi ohun gbogbo to n waye nibi idibo ọhun to yin leti