Ekiti Election: Ìhà wo ni aráàlú kọ sí àsà ‘See and Buy’

Àkọlé fídíò,

Ekiti Election: Àwọn aráàlú ń tahùn síra wọn lórí ìbò rírà

‘See and Buy’ ni aṣa tuntun to jẹ jade lasiko eto idibo sipo gomina to waye lọjọ kẹrinla, oṣu Keje ọ́dun 2018 ni ipinlẹ Ekiti.

Awọn oludibo ṣalaye pe, igbesẹ naa nii ṣe pẹlu gbigba owo gẹgẹ bi oludibo, lẹyin ti ẹgbẹ́ oselu ti o dibo fun ba ri i daju pe ẹgbẹ wọn lo di ibo rẹ fun.

Saaju ki oludibo to lọ tẹka sori iwe pelebe ti yoo fi dibo, ni awọn asoju ẹgbẹ oselu to n 'mojuto bi nkan se n lọ nibi eto idibo to n lọ lọwọ', yoo ba oludibo naa sọrọ lori iye ti wọ̀n yoo fun to ba fi dibo fun ẹgbẹ wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Baba Khadijat Oluboyo jẹ́rìí ọmọ rẹ̀

Nigba miran ẹwẹ, awọn to ti kọkọ dibo, to si ṣe 'See and Buy' ni yoo ṣalaye fun awọn akẹgbẹ wọn, bi igbesẹ naa ṣe n lọ.

Iriri awọn akọroyin BBC lori bi ‘See and Buy’ ṣe n ṣiṣẹ

Oludibo yoo gba iwe pelebe ti yoo fi dibo, yoo lọ si ibi ti yoo ti tẹka.

To ba ti tẹka si iwaju ami ẹgbẹ to fẹ ẹ dibo rẹ fun, ni yoo na iwe pelebe naa soke lati fi han aṣoju ẹgbẹ oṣelu ti wọn yan, to si duro si ọkan, nitosi ibi ti wọn ti n tẹka, lati fihan wọn pe ẹgbẹ wọn ni oun dibo fun.

Aṣoju ẹgbẹ naa yoo mi ori si i lọọkan, lati fihan pe oun ti ri ibi ti o dibo rẹ si.

Àkọlé àwòrán,

Alaga ajọ INEC nipinlẹ Ekiti ni ko si ohunkohun ti ajọ INEC lee ṣe si ọrọ naa.

Lẹyin eyi ni oludibo naa yoo to lọ ju iwe pelebe naa sinu apoti ti ajọ INEC ti pese, ti yoo si kuro nibudo idibo lọ si ibi pataki ti wọn ti pese silẹ lati lọ gba owo ibo to di.

Asoju ẹgbẹ oṣelu naa, ti oludibo fi iwe idibo rẹ han, yoo mi ori lati ọọkan to wa, lati sọ fun ẹni to n sanwo pe oludibo to de ọdọ rẹ dibo fun ẹgbẹ wọn.

Kin ni ajọ INEC n ṣe lori asa 'See and Buy'?

Akọroyin BBC to ba Ọjọgbọn Abdulganiyu Raji, tii ṣe alaga ajọ INEC nipinlẹ Ekiti, to si tun dari eto idibo naa sọrọ, jábọ̀ pé, o ni ko si ohunkohun ti ajọ INEC lee ṣe si ọrọ naa.

O ni 'ojuse ti ofin la kalẹ fun ajọ eleto idibo ni lati se kokari bi eto idibo yoo ṣe waye, kii ṣe lati tọpinpin ihuwasi awọn oludibo lasiko ti wọn n dibo. O ni ojuṣe awọn agbofinro ni lati mu ẹnikẹni to ba ṣe bẹẹ.

Àkọlé àwòrán,

See and Buy nii ṣe pẹlu gbigba owo gẹgẹ bi oludibo, lẹyin ti ẹgbẹ́ oselu ti o dibo fun ba rii daju pe ẹgbẹ wọn lo di ibo rẹ fun.

Ṣugbọn awọn agbofinro naa ti faake kọ̀ri lori eyi, ti wọn si ni ojuṣe awọn ni lati pese aabo nibudo idibo, ki i ṣe lati mojuto iwa bii 'See and Buy.'

Kin ni awọn araalu wa n sọ lori asa ‘see and Buy’ ?