Small Doctor: Mo kórira igbó, ọtí àti sìgá nítorí màmá mi lòdì si

Small Doctor: Mo kórira igbó, ọtí àti sìgá nítorí màmá mi lòdì si

Ìlúmọ̀ọ́ká òǹkọrin tàka-súfé, Temi Adekunle, tí gbogbo èèyàn mọ̀ sí Small Doctor ti sọ fún BBC Yorùbá pé kò yé òun, ìdí tí ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ fi ń dá ẹ̀mí ara wọn ní ègbodò láti ipasẹ̀ mímu òògùn olóró.

Small Doctor fi kun pé ìyá òun, ‘ìyá Tíṣà’ kò nífẹ́ sí irú ìwà àìdáa yìí,tí òun kìí kọrin nípa rẹ̀ nítorí bó ṣe ń ba ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ láyé jẹ́.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bákan náà ló ní kíláásì kìnní-ní, ní ilé ẹ̀kọ́ girama àgbà, SS1, ni òun ti bẹ̀rẹ̀ orin kíkọ, tí kò sì rọrùn rárá láti se àwo orin tí yóò jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà.

Small Doctor ní omi máa ń bọ́ lójú òun lásìkò tí òun bá rántí àkókò ìbẹ̀rẹ̀ òun tí kò rọrùn rárá, àti bí wọn kìí ṣe pe òun sí agbo eré.