World Cup: Bàálù tíjọba fi ránsẹ́ ló kó wọn wálé

Àwọn ọmọ Nàíjíríà tó há sí Russia to ń padà bọ̀ wálé

Oríṣun àwòrán, Yulia Siluyanova

Àkọlé àwòrán,

Àwọn ọmọ Nàíjíríà tó lé ní igba ló há sí Russia láì ní owó ọkọ̀ lẹ́yìn tí ife ẹ̀yẹ àgbáyé parí tán.

Orire ti gbe alawo rere pade awọn ọmọ Naijiria to ha si orilẹ-ede Russia lẹyin ife ẹyẹ agbaye to sẹsẹ pari losu keje ọdun 2018.

BBC Yoruba gbọ pe o le ni igba awọn ọmọ Naijiria ti ọna pin mọ lati pada sile lẹyin ti ẹgbẹ agbabọọlu ilẹ wa, Super Eagles fidi rẹmi ninu idije naa, ti ko si si ọna abayọ fun wọn lati pada si ilẹ baba wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Small Doctor: Mo kórira igbó, ọtí àti sìgá nítorí màmá mi lòdì si

Amọ ijọba apapọ ilẹ wa ti fi baalu kan ransẹ si Russia lati lọ ko awọn ‘Atipo’ ojiji yii pada sile.

Oríṣun àwòrán, Yulia Siluyanova

Àkọlé àwòrán,

Amọ ijọba apapọ ilẹ wa ti fi baalu kan ransẹ si Russia lati lọ ko awọn 'Atipo' ojiji yii pada sile.

Ni alẹ ọjọbọ, ni baalu naa gunlẹ́ si orilẹ-ede Russia, to si gbera ni aago mẹfa aarọ ọjọ Ẹti lati kọkọ ko aadọta ninu awọn ololufẹ ere bọọlu naa pada sile.

Gẹgẹ biirofin kan ti ọkan lara ọmọ Naijiria to fi orilẹ-ede Russia se ibujoko, to n se iranwọ fawọn arinrin ajo naa lati rọna abayọ, ti fi to BBC leti, irinajo lati orilẹ-ede Russia si Naijiria to wakati mẹjọ, ti ireti si wa pe nigba ti yoo ba fi di aago meji ọsan ọjọ Ẹti, awọn arinrinajo ọhun yoo gunlẹ si papakọ ofurufu Muritala Muhammed nilu Eko.