Adeoti: àwọn ọmọ ẹgbẹ́ míran tún ti kòwé fipò sílẹ̀ l'Ọsun

Moshood Adeoti Image copyright Adeoti/facebook
Àkọlé àwòrán Awọn oludije to yẹba ni Moshood Adeoti, tii se akọwe ijọba ipinlẹ Ọsun, Peter Babalọla ati Senatọ Babajide Ọmọworarẹ.

Ọmọ ẹgbẹ́ APC mẹ́sàn-án ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ló ti kòwé fipò sílẹ̀ báyìí tí wọn sí ti lọ sí ẹgbẹ́ oṣèlú Action Democratic Party (ADP).

lOhun to n ṣẹlẹ yii lo ti di àǹkóò fawẹli kaakiri ipìnlẹ ni Naijiria bẹrẹ lati ile igbimọ aṣofin agba de tipinlẹ lasiko yii.

Awọn eniyan n soro pe ohun tó ń ṣẹ́lẹ̀ nínú ẹgbẹ́ òṣèlú All progressives progress (APC) nípìnlẹ̀ Ọsún láìpẹ́ yìí kò bójúmú.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFadele: Dán an wò, lóbí ìyá ọ̀kẹ́rẹ́ ni a fi ọ̀rọ̀ ọ̀kadà náà ṣe

Gẹ́gẹ́ bí ìwé ti wọn jo kọ láti fi ipo sílẹ̀ ṣe sọ, tí o sì tẹ BBC lọ́wọ́ ní pé ìfẹ́nukò àwọn ará ìlú àti àwọn tọ́rọ̀kàn ní ẹkùn mẹ́tẹẹ̀ta ní ìpínlẹ̀ Ọsun ló fa ìdí abájọ tàwọn ṣe lọ sí ẹgbẹ́ òṣèlú ADP.

Wọn ní àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń ṣẹ́lẹ̀ nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC nípìnlẹ̀ Ọsún láìpẹ́ yìí jẹ́ ohun tó lòdì sí ẹ̀kọ́ tó bá ojú mú ninu iṣejọba awa-ara-wa.

Awọn tó fi ipò sílẹ̀ ní

  • Azeez Adesiji ìgbákejì alága ẹgbẹ́ ní ìpínlẹ̀
  • Tajudeen Agbeti
  • Ademola Bamidele
  • Rasheed Bakare àti
  • Morakinyo Akintola
  • Wale Adunola
  • Bakare Idayat
  • Ogundare Afolabi
  • Sikiru Kareem.

Èrò ẹgbẹ́ òṣèlú APC lẹ́yìn ti wọ́n yapa lọ:

Kunle Oyatomi, to jẹ olúdari ìbánisọ̀rọ̀ nínú ẹgbẹ́ òṣèlú All progressives Congress ba ṣalaye pe kò sí ohun tuntun labẹ ọrun mọ.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, nínú ìwé tó fi sọwọ́ si BBC Yorùbá o ṣàlàyé pé, gbogbo ènìyàn ló ní ẹ̀tọ́ láti fí ẹgbẹ́ sílẹ̀ sùgbọ́n èrèdí ti wọn fi fi égbẹ́ sílẹ̀ kò tẹ̀wọ̀n tó.

'wọn rò pé pipariwo pé àwọn ń lọ pẹ̀lú ọmọ ẹ̀yìn ẹgbẹ̀rún mẹ́fà ní yóò mú wọn jáwé olúbori fun ìdìbò gomínà tó ń bọ̀, wọn ń gbéra wọn gẹṣin aáyán lásán ni.'Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Kin lo ti ṣẹlẹ ninu APC ipinlẹ Ọṣun

Awọn oludije ti wọn jade ninu idibo abẹle ni Moshood Adeoti, tii se akọwe ijọba ipinlẹ Ọsun, Peter Babalọla ati Senatọ Babajide Ọmọworarẹ.

Atẹjade kan ti Sẹnetọ Ọmọworarẹ́ fisita, eyi ti oludari feto iroyin rẹ, Tunde Dairo fọwọsi ni aarọ ọjọ Ẹti ni ilu Osogbo ni "nitori ọ̀pọawọn isẹlẹ oselu to n waye, eyi to kọja akoso, ni oun ko se ni fi awọn asoju oun si wọọdu kọọkan tabi se iwuri fawọn alatilẹyin oun lati lọ, bẹẹ si ni oun ko ni lo ohun alumọọni oun feto idibo abẹnu naa."

O ni igbesẹ naa lo wa lati ri daju pe isọkan wa ninu ẹgbẹ oselu naa ko lee bori idibo gomina ti yoo waye lọjọ kejilelogun osu kẹsan ọdun yii.

Àkọlé àwòrán Awọn oludije to yẹba ni Moshood Adeoti, tii se akọwe ijọba ipinlẹ Ọsun, Peter Babalọla ati Senatọ Babajide Ọmọworarẹ.

Bakan naa, akọwe ijọba ipinlẹ Ọsun, Moshood Adeoti, ninu atẹjade toun naa fisita fawọn akọroyin, lo ti sisọ loju ọrọ yii, pẹlu awijare pe oun fẹ fara mọ ipinnu ẹkun idibo oun, tii se ẹkun idibo iwọ oorun guusu Ọsun, eyi to ni oun to nii kopa ninu eto idibo abẹnu naa.

O wa parọwa sawọn ololufẹ rẹ pe oun si n dije fun ipo gomina ipinlẹ Ọsun o, bi o tilẹ jẹ pe oun ko ni kopa ninu eto idibo abẹnu APC. Eyi si lo n mu kawọn eeyan maa fura pe o seese ko fẹ lọ sinu ẹgbẹ oselu miran.

Oludije kẹta, Peter Babalọla ni tiẹ kede pe oun ti yẹba ninu idije naa lati ori ẹrọ ibaraẹni sọrọ.