LASG: LASTMA, àtàwọn àjọ míràn ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ dídẹ́kun súnkẹrẹ ọkọ̀ lásìkò ọdún

Igboro ilu Eko

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ijọba ipinlẹ Eko ti ṣeleri pe ko lee si wọlu-kọlu ọkọ ni ipinlẹ Eko lasiko ayẹyẹ opin ọdun

Ijọba ipinlẹ Eko ti ṣeleri pe ko lee si wọlu-kọlu ọkọ ni ipinlẹ Eko lasiko ayẹyẹ opin ọdun.

Kọmiṣọna feto irinna ọkọ nipinlẹ Eko, Ladi Lawson lo ṣalaye yii lẹyin ipade idakọnkọ kan to waye laarin awọn ajọ ati ileeṣẹ eto irinna nipinlẹ Eko ni ọjọbọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Ọba Olutayọ: ìgbésẹ̀ Ọọni àti Alaafin ti ń mú ìṣọ̀kàn dé sáàrin àwọn Ọba Yorùbá

Ọgbẹni Lawson ni ijọba ti gbe eto kalẹ eleyii ti yoo rii daju pe igbokegbodo ọkọ n lọ bi o ti tọ lai si idiwọ ni bi ayẹyẹ opin ọdun ṣe n sunmọ.

O ni idi ti gomina Akinwumi Ambọde fi pe ipade idakọnkọ naa ni lati ṣe eto ati ilana ti yoo wa iyanju si wahala sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ pẹlu abo fun ẹmi ati dukia lasiko ọdun.

Bakan naa ni ọga agba ajọ LASTMA, Chris Olakpe pẹlu ṣalaye pe wọn yoo tete ṣe eto ẹkọṣẹ fun awọn ẹgbẹrun kan oṣiṣẹ ti ajọ naa ṣẹṣẹ gba laipẹ yii ki wọn lee bs si ẹnu iṣẹ ki asiko ọdun to wọle.

Ìjàmbá reluwe ní Agége pa èèyàn mẹ́jọ

Oríṣun àwòrán, LASTMA

Àkọlé àwòrán,

Bọọsi kan to duro soju irin reluwe lo fa sababi ijamba naa

Eeyan mẹjọ ti di ero ọrun ni aarọ ọjọ Ẹti, nigba ti ọkọ reluwe kan kọ lu ọkọ akero kan ni adugbo Agege.

Ijamba ọhun, to see dena lo waye nigba ti ọkọ akero kan duro si oju ọna reluwe.

Oríṣun àwòrán, LASTMA

Àkọlé àwòrán,

An osi panpana ti wa nibi i naa lati palẹ ajoku ọkọ mọ

Nigba ti reluwe fọn pe ko kuro nibẹ́, wadu-wadu to n se lo mu ki awakọ naa fi ọkọ rẹ si rifaasi lai mọ, to si mu ki reluwe naa kọlu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Small Doctor: Mo kórira igbó, ọtí àti sìgá nítorí màmá mi lòdì si

Ijamba naa si lo mu ki ọkọ akero naa gbina, amọ ori ko awọn ero to wa ninu rẹ yọ.

Nigba to n fi idi isẹlẹ ọhun mulẹ fun BBC Yoruba, ọga agba fun ajọ to n se akoso oju popo nipinlẹ Eko, LASTMA, Ọgbẹni Ọla Musa salaye pe lootọ ni isẹlẹ naa waye.

Ẹni kan to sọ nipa isẹlẹ naa loju opo twitter rẹ @Oshofaze, to ni isẹlẹ naa soju oun,lo kede pe eeyan mẹjọ lo ku.

Igba akọkọ kọ ree ti irufẹ ijamba ọkọ oju irin yoo maa waye ni agege. Bẹẹ ba si gbagbe, bakan naa ni irufẹ isẹlẹ yii waye lọdun 2017 nigba ti ọ̀kọ oju irin naa ya kuro loju opo rẹ.

Oríṣun àwòrán, LASTMA

Àkọlé àwòrán,

Igba akọkọ kọ ree ti irufẹ ijamba ọkọ oju irin yoo maa waye ni agege

Amọ o ni oun ko tii lee sọ ni pato, iye eeyan to ba isẹlẹ naa rin.

Nibayii na, ajọ Lastma tisisẹ lati mu ki ohun gbogbo pada bọ sipo lagbegbe naa.

Àkọlé fídíò,

Ìran kan si ìkejì ló n gbèrò láti ṣe ìrú ìgbéyàwo àjùmọ̀ṣe 'Shao' fọ́mọ wọn