Ekiti Election: Fayẹmi ní òun kò ní se àsìse bíi ìjọba tó ń lọ

Fayemi ati Buhari

Oríṣun àwòrán, @KBStGovt

Àkọlé àwòrán,

Fayẹmi tun lo asiko naa lati fi iwe ẹri ti INEC fun han Aarẹ Muhammadu Buhari

Gomina ti wọn sẹsẹ dibo yan nipinlẹ Ekiti, Kayọde Fayẹmi ti sọ pe oun yoo ṣewadi gbogbo ohun to waye ninu iṣejọba Ekiti lati bi ọdun mẹrin sẹyin.

Fayẹmi sọrọ naa lẹyin to ṣe abẹwo si Aarẹ Muhammadu Buhari nile aarẹ to wa nilu Abuja.

Fayẹmi ni 'oun yoo 'se iwadi eto iṣakoso ipinlẹ Ekiti labẹ iṣakoso Gomina Ayọdele Fayoṣe to n kogba wọle, fun anfaani eto iṣejọba to mọyan lori.

Oríṣun àwòrán, Fayemi/Fayose/Facebook/Twiter

O ni 'oun yoo wadi iye to wọle si apo ijọba ati idi ti owo awọn oṣiṣẹ ko fi jẹ sisan.

Fayẹmi, to ti figba kan jẹ minisita fun idagbasoke iwa kusa ati irin tutu, tun lo asiko naa lati fi iwe ẹri moyege ti ajọ eleto idibo Naijiria, INEC fun lẹyin eto idibo to ti jawe olubori han aarẹ Muhammadu Buhari.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Ile Igbimo Asofin Ekiti: ìjòkó jẹ́? A ko fẹ́ kú o

Bi o tilẹ jẹ pe o sọ pe oun yoo yẹ awọn iwe akọsilẹ ijọba, Fayẹmi ni afojusun oun ki i sẹ lati tanna wadi Fayose tabi igbakeji rẹ, Olusọla Ẹlẹka.

O ni afojusun igbesẹ naa ni lati ri i daju pe awọn ko ṣe aṣiṣe t'awọn to kọja sẹ. Ati lati fun awọn eniyan ipinlẹ Ekiti ni eto iṣejọba to dara.

Bakan naa ni Fayẹmi ni oun ti bẹrẹ si ṣe awọn to yẹ ni imurasilẹ fun eto igbajọba.

Oríṣun àwòrán, @VoteFayemi

Àkọlé àwòrán,

Fayẹmi ni oun ti bẹrẹ si ṣe awọn to yẹ ni imurasilẹ fun eto igbajọba.

Ati pe ohun yoo ṣe igbelewọn awọn dukia ti Ekiti ni, to fi mọ awọn ohun to n nawo le lori.

Igbakeji niyi ti ikede yoo jade lẹyin eto idibo gomina to waye nipinlẹ Ekiti lọjọ kẹrinla, oṣu Keje, ọdun 2018, nipa ṣiṣe iwadi eto iṣakoko Gomina Fayose. Ajọ to n gbogun ti iwa ijẹkujẹ ni Naijiria, EFCC, ti kọkọ fi ikede kan sita loju opo Twitter lati wadi mago-mago to waye lori idasilẹ ile adiyẹ kan ti ijọba ipinlẹ ekiti ṣe lasiko ti Fayose fi kọkọ ṣe gomina laarin ọdun 2003 si 2006. Ṣugbọn ajọ EFCC pada pa ikede naa rẹ.