Idibo Ọsun : Adeleke,Ogunbiyi, Adejare ati Nathaniel lo n dije

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIdibo Ọsun : Adeleke,Ogunbiyi, Adejare ati Nathaniel lo n dije

Iroyin to n tẹwa lọwọ sọ pe nkan o rọgbọ nibi eto idibo abẹlẹ ti ẹgbẹ oselu PDP, lẹyin ti awọn ọdọ kan gbe igi lati fi se ikọlu si Alaga ẹgbẹ oselu PDP ni ipinlẹ naa, Sola Adagunodo.

Awọn ọdọ to n se agbatẹru fun oludije, Sẹnatọ Nurudeen Adeleke fi ẹsun kan Adagunodo wi pe o wa lẹyin Akin Ogunbiyi to jẹ ọkan ninu awọn oludije si ipo gomina naa.

Amọ, awọn ẹsọ eleto aabo ti mu ohun gbogbo pada bo sipo, lẹyin ti awọn ọdọ naa ba ọkọ Ajọ INEC to wa nibe jẹ.

Àkọlé àwòrán Awọn amoye ni idije naa wa laarin Akin Ogunbiyi, Fatai Akinbade ati Ademola Adeleke

Adeleke,Ogunbiyi, Adejare ati Nathaniel lo n dije

Awọn ẹlẹto idibo ni ipinlẹ Ọsun ti bẹrẹ si ni ka ibo awọn oludije ninu eto idibo abẹnu lati mọ ẹni ti yoo soju ẹgbẹ oselu PDP nipinlẹ Ọsun ni idibo si ipo gomina ti yoo waye ni Osu Kẹsan, ọdun yii.

Àkọlé àwòrán Tani yóò pegedé nínú ìbò abẹ́lé PDP l‘Ọ́sun?

Ọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ oselu PDP lo ti pe jọpọ si ile itura GMT ni ilu Osogbo, ti eto idibo abẹnu naa ti n waye.

Ni owurọ Ọjọ Satide ni awọn oludibo di ibo lati yan ẹni ti yoo gbẹ asiya ẹgbẹ oselu PDP, atiwipe awọn oloye ẹgbẹ ati awọn agbofinro ti peju sibi aye idibo naa.

Àkọlé àwòrán Ènìyàn kan láàáarín àwọn olúdíje mẹ́rin yìí ni yóò láǹfààní àti kópa nínú ìdìbò Gomina ìpínlẹ̀ Osun.

O le ni ẹgberun mẹta ọmọ ẹgbẹ lati ijoba ibile ogbọn ti yoo kopa ninu yiyan oludije fun ẹgbẹ ninu idibo naa

Wayi o, awon oludije kan ninu awọn to n dije fun ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oselu PDP ti kede pe awọn ko ni kopa ninu idibo naa mọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÒsìsẹ́-fẹ̀yìntì Èkìtì: À ń bẹ̀bẹ̀ fún gómìnà tí yóò sàánú wa

Lara awọn oludije naa ni ati ri Ojogbọn Durotoye Adeolu,Lere Oyewumi,Ayoade Adewopo ati olori ile asofin ipinle Osun nigba kan ri Adejare Bello.

Awọn amoye ni idije naa wa laarin Akin Ogunbiyi, Fatai Akinbade ati Ademola Adeleke.

Iroyin fikun wipe yàtọ̀ sí Akogun Lere Oyewumi tó yẹba fún Ademola Adeleke, àwọn Olùdíjé tó kù yẹba fún Akin Ogunbiyi.