Osun Election: Ìbò méje péré ni Adeleke fi fẹ̀yìn Adebiyi janlẹ̀

Aworan Ademola Adeleke Image copyright Ademola Adeleke/Facebook
Àkọlé àwòrán Adeleke ni yóò kojú ọgbẹni Gboyega Oyetola ti ẹgbẹ òṣèlú APC nínú ìdìbò Gómìnà ìpínlẹ̀ Osun

Sẹ́nétọ̀ Ademola Adeleke ni yóò máa ṣojú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP nínú ìdìbò sípò Gomina tí yóò wáyé ní Ìpínlẹ̀ Osun.Adeleke ni ìbò 1569 ṣáájú Akin Ogunbiyi tó ní ìbò 1562.

Àkọlé àwòrán Ìbò méje péré ni Adeleke fi fẹ̀yìn Adebiyi janlẹ̀

Alaga eto ìdìbò náà, tó tún jẹ́ Gomina Ipinle Bayelsa Seriake Dickson ló kéde Adeleke gẹ́gẹ́ bí ẹni tó jáwé olú borí, lẹ́yìn tí wọ́n ka ìbò náà ní ẹ̀ẹ̀meji ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Adeleke ni yóò kojú ọgbẹni Gboyega Oyetola ti ẹgbẹ òṣèlú APC nínú ìdìbò Gómìnà ìpínlẹ̀ Osun tí yóò wáyé ní ọjọ kejilelogun oṣù kẹsán ọdún 2018.

Adeleke ni Sẹ́nétọ̀ tó n sójú ẹkùn ìdìbò iwọ òrun ìpínlẹ̀ Osun ní ilé aṣòfin àgbà.