Osun Election: Babatunde Loye, Bunmi Ibiloye ati Pade Okunọla lo dije fun ibo abẹnu Accord

aWọN OLUDIJE FUN IPO GOMINA FẹGBẹ OSELU aCCORD
Àkọlé àwòrán Sugbọn eto idibo abẹnu ẹgbẹ oselu Accord naa ko lọ lai jẹ pe o ni awọn isẹlẹ kan ninu

Saa idibo abẹnu lati yan awọn oludije ti yoo soju awọn ẹgbẹ oselu to gbode kan nipinlẹ Ọsun, ko yọ ẹgbẹ oselu Accord naa silẹ.

O le ni awọn asoju to wa lati awọn ijọba ibilẹ toto ọgbọn ati ijọba ibilẹ onidagbasoke kan, ti wọn peju silu Osogbo ni ọjọ abamẹta lati wa yan ẹniti yoo soju ẹgbẹ naa bi oludije gomina.

Awọn oludije mẹta lo fa ipo naa mọ ara wọn lọwọ ninu ẹgbẹ oselu Accord. Awọn oludije fun ipo gomina naa ni Babatunde Loye, Bunmi Ibiloye ati Pade Okunọla.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSegun Ọdẹgbami: Mo kọ̀ láti lọ sí APC àti PDP nítorí ń kò fẹ́ ní ‘Bàbá ìsàlẹ̀’

Lẹyin ọ rẹyin ti ibo naa pari, Pade Okunọla lo bori awọn eeyan meji ti wọn dijọ dije pẹlu ibo mọkanlelogoje.

Sugbọn eto idibo abẹnu ẹgbẹ oselu Accord naa ko lọ lai jẹ pe o ni awọn isẹlẹ kan ninu, gẹgẹ bo se wa pẹlu awọn ẹgbẹ oselu yoku.

N se si ni awọn ọlọpa duro wa wa wa sibẹ lati ri daju pe ọfọn kankan ko firu na igba nibi idibo abẹnu Accord naa.

Àkọlé àwòrán Lẹyin ikede esi ibo yii, ni wọn rọ gbogbo awọn asoju lati maa lọ sile koowa wọn.

Bi alaga ẹgbẹ osleu Accord nipinlẹ Ọsun, Hon Fanibẹ si sen kede esi ibo naa, ni iroyin gbalẹ kan pe awọn gende agbebọn kan ti wa layika ibẹ, lati da rugudu silẹ́ lẹyin ikede esi ibo naa.

Lẹyin ikede esi ibo yii, ni wọn rọ gbogbo awọn asoju lati maa lọ sile koowa wọn.

Bẹẹ ba si gbagbe, ni ọjọ abamẹta ti ẹgbẹ oselu PDP n se eto idibo abẹnu tiẹ ni ilu Osogbo, naa ni ẹgbẹ oselu Accord n se tiẹ ni ẹgbẹ kan lati yan ẹni ti yoo soju rẹ gẹgẹ bii gomina.

Àkọlé àwòrán Lẹyin ọ rẹyin ti ibo naa pari, Pade Okunọla lo bori awọn eeyan meji ti wọn dijọ dije pẹlu ibo mọkanlelogoje.

Sẹnatọ Ademọla Adeleke lo fi ibo meje fẹyin alatako rẹ, Akin Ogunbiyi janlẹ lati di oludije fun ipo gomina fẹgbẹ oselu PDP>

ẸBakan naa ni ẹgbẹ oselu APC ti se eto idibo abẹnu lati yan ẹniti yoo soju rẹ gẹgẹ bii gomina ninu idibo to n bọ losun kẹsan ọdun yii lọjọ Ẹti.

Gboyega Oyetola, tii se olori awọn osisẹ ni ọọfisi gomina nipinlẹ Ọsun si lo pegede ninu ìdìbò abẹ́nú APC naa.