Ikú alaga PDP: Niyi Aborisade ni alága PDP ní ìjọba ìbílẹ̀ Apápá

Niyi Aborisade alaga PDP ni Apapa
Àkọlé àwòrán Wọn gbe Niyi Aborisade lọ ile iwosan kan ni Obalende, sugbọn ẹ̀pa kò bóró mọ́

Àlaga ẹgbẹ oṣelu PDP ni ijọba ibilẹ Apapa ni Ipinlẹ Eko, Niyi Aborisade, ti gbẹmii mi bayi, lẹyin ti awọn janduku ti yinbọn pa nibi ipade kan to waye ni ọjọ Abamẹta ni Eti Osa.

Ileesẹ ọlọpaa Ipinlẹ Eko sọ wipe, ipade awọn alaga ijọba ibilẹ ẹgbẹ PDP nilu Eko waye ni adugbo Igbosuku lopopona marosẹ Lekki si Ẹpẹ to wa ni ijọba ibilẹ Eti Osa, nibi ti ija ti bẹ silẹ laarin igun (faction) meji ẹgbẹ naa.

Inu ija naa ni wọn ti yinbọn si ẹsẹ Aborisade to jẹ ọkan gboogi ninu awọn alaga ijọba ibilẹ PDP n'Ipinlẹ naa.

Agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa Ipinlẹ Eko, Chike Oti, ni wọn gbe Aborisade digbadigba lọ ile iwosan First Consultant to wa ni Obalende, sugbọn wọn ko le doola ẹmi rẹ.

O ni awọn meji miiran lo fara pa nibi iṣẹlẹ naa, ti wọn si n gba itọju ni awọn ni ile iwosan kan ni Ajah.

Oti ni kete ti ọga ọlọpaa ni Ipinlẹ Eko, Edgal Imohimi gbọ nipa iṣẹlẹ naa, lo paṣẹ fun ọga ọlọpaa agbegbe Area 'J' Elemoro, lati gbe awọn to lọwọ ninu ọrọ naa ti mọle.

Awọn ti wọn ti wa ni ahamọ ọlọpaa bayii ni awọn alaga PDP fun ijọba ibile Eti Osa, Surulere, Amuwo Odofin, Mushin ati Lagos Island.

Imohimi ti ni ki wọn gbe ọrọ naa lọ ẹka ileeṣẹ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ to wa ni Panti, Yaba.