#EndSARS: Lẹ́yin àṣẹ́ adelé Ààrẹ Osinbajo, ọgá ọlọ́pàá yan orúkọ tuntun fun SARS

Ibrahim Idris

Oríṣun àwòrán, @NG_Police

Àkọlé àwòrán,

Idris ko ba awọn oniroyin s'ọrọ lẹyin ipade rẹ pẹlu aarẹ

Ọga agba ileeṣẹ ọlọpàá Ibrahim Idris ti kede ayipada orukọ, SARS, lẹyin ti adele Ààrẹ orílè-èdè Naijiria,Yemi Osinbajo pàṣẹ ko ṣe àtúnto ẹka naa.

Ni bayi, o ni Federal Special Anti Robbery Squad(FSARS) ni SARS yoo maa jẹ.

Bakanna lo ni gbogbo ẹka SARS teleri ri to wa labẹ ti bọ si abe FSARS pẹlu iyipada tuntun yi.

Eyi nikan kọ, Kọmiṣọna ọlọpàá kan ni yoo maa dari ajọ naa bayii, yoo si maa jẹ abọ fun ẹka ileeṣẹ olopaa ni Abuja to n ri si iwa ọdaran.

Sugbọn awọn ọmọ Naijiria ti n se eemọ lori igbese yi.

Ni oju opo Twitter ibeere ti awọn eeyan n bere ni pe kini iyato to wa laarin SARS ati FSARS ati wipe ṣebi FSARS lorukọ ti wọn ti n jẹ latilẹ tẹlẹ ri?

Lọjọ isẹgun ni agbẹnusọ fún adele Ààrẹ, Laolu Akande, fi ọrọ síta loju opo Twitter pé Adele Aarẹ Yemi Osinbajo ti pasẹ fun ọgá ọlọpaa lati se atunto SARS.

Osinbajo so wí pé ọmọ tuntun ti atunto SARS yoo bí gbọdọ máa ṣíṣe lọnà to tọ ati eyi to yẹ.

gbọdọ kojú mọ iṣẹ ti wọn gbe kale fun un ti ṣe didẹkun iwa adigunjale àti ìwà ajinigbe tó fí mọ mímú àwọn tí wọn hù ìwà tó jẹ mọ àwọn ẹṣẹ wọn yí.

Adele Ààrẹ Osinbajo tẹsíwájú pé o di dandan ki àwọn oṣiṣẹ SARS ni àmì idanimo lara wọn ní gbogbo ìgbà tí wọn bá n ṣíṣe wọn.

Ti a kò bá gbàgbé oríṣiríṣi iriri lo tí n waye lati ọdọ ara ìlú nípa ìhùwàsí àwọn oṣiṣẹ SARS

Ẹsun iseku pa awọn ọmọ Naijiria nipakupa jẹ ọrọ ti awọn ọmọ Naijiria ko le mẹnu kuro nibẹ lati bii oṣu meloo kan.

Tóun tí bí ẹnu ti ṣe n kun wọn,ilé iṣẹ ọlọpa lorílè-èdè Nàìjíríà ni awon kò ri ìdí tí wọn yóò fi kagba Sars wọlé Bo tilẹ jẹ pe awọn yoo gbe igbeṣẹ lati ri pe wọn ṣe atunto ẹka SARS naa.

Àkọlé fídíò,

ọ̀gá ọlọ́pàá sọ̀rọ̀ lórí SARS

Àkọlé fídíò,

SARS ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti yọ àwọn ọ̀bàyéjẹ́ kúro

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: