Abuja-Kaduna: Àwọn arìnrìn àjò ní àwọn ọlọ́pàá kò leè ta pútú

Opopona Abuja si Kaduna Image copyright @Omojuwa
Àkọlé àwòrán Àwọn ajínigbé ti sekú pa ológun kan, wọ́n tún jí ọ̀pọ̀ arìnrìniajò lọ lójú ọ́na marosẹ̀ Abuja sí Kaduna lọ́jọ́ Àìkú.

Awọn ajinigbe mẹwa ni wọn ṣọsẹ loju ọna mọrosẹ Abuja si Kaduna lọjọ Aiku nibi ti wọn ṣeku pa ọmọ ologun kan ti wọn si ji ọpọ arinrinajo gbe.

Iṣẹlẹ naa lo ṣẹlẹ lẹba abule Gidan Busa to wa laarin Jere ati Kateri lopopona ọhun.

Arinrinajo kan tori kọyọ Mohammed Sheriff fidi rẹ mulẹ pe, awọn ọdaran naa ṣọsẹ fun bii wakati kan loju ọna naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBọlanle Aliyu: N kò nílò bàbá ìsàlẹ̀ láti di gómìnà

Arinrinajo miran jẹri wipe, ọlọpa kan naa wa lara awọn ti wọn padanu ẹmi wọn ninu iṣẹlẹ ọhun.

Awọn ti iṣẹlẹ naa tun ṣoju wọn sọ pe, awọn oṣisẹ eleto aabo ko le doju jọ awọn janduku ọhun.

Wọn ni awọn ọlọpaa naa sọ pe awọn nilo iranwọ si lati le koju awọn ajinigbe naa.