Ọ̀sun Election: Akin Ogunbiyi àti Moshood Adeoti kọ èsì ìbò

Ami idamọ ẹgbẹ oselu PDP ati APC Image copyright @akmediaonline
Àkọlé àwòrán Akin Ogunbiyi àti Moshood Adeoti kọ èsì ìbò abẹnu ẹgbẹ koowa wọn

Ọmwe Akin Ogunbiyi, ti oun ati Senatọ Ademọla Adeleke dijọ dije ninu ibo abẹnu fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oselu PDP nipinlẹ Ọsun, ti fariga lati faramọ esi ibo abẹnu ti wọn kede naa lọjọ Abamẹta, to si leri leka pe oun yoo gbe igbesẹ lati wa iyipada lori ọrọ yii ninu ẹgbẹ naa.

Lasiko to n bawọn akọroyin sọrọ lori abajade ibo abẹnu PDP nipinlẹ Ọsun, eyi to se ni ilu Ile-Ogbo, tii se ilu abinibi rẹ, Ogunbiyi ni bi wọ́n se se ayẹwo orukọ awọn asoju to dibo, eto idibo ati kika esi ibo ni wọn se lati gbe lẹyin alatako oun, Senatọ Ademọla Adeleke.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBọlanle Aliyu: N kò nílò bàbá ìsàlẹ̀ láti di gómìnà

O ni nigba ti wọn tun ibo naa ka ni ẹẹkeji, sebi ibo oun tun lowura ju ti akọkọ lọ, eyi to fihan pe eto idibo naa lọwọ magomago ninu, ti ko si tẹ oun ati awọn alatilẹyin oun lọrun.

"Mo n fi da yin loju pe awọn dibo fun mi pupọ, ọpọ̀ awọn asoju to dibo lo n se temi, lagbara Ọlọrun, maa gba ipo mi pada bii oludije fun ipo gomina fẹgbẹ oselu PDP nipinlẹ Ọsun.

Bakan naa, akọwe ijọba ipinlẹ Ọsun, Alhaji Moshood Adeoti, toun naa kopa ninu ibo abẹnu APC lati yan ẹniti yoo soju ẹgbẹ oselu naa, ninu eto idibo gomina to n bọ losu kẹsan ọdun 2018 nipinlẹ Ọsun, amọ to fidi rẹmi, ti kọwe pe oun ko se ẹgbẹ oselu APC mọ.

Image copyright @Akinogunbiyi48
Àkọlé àwòrán Ogunbiyi ni bi wọ́n se se ayẹwo orukọ awọn asoju to dibo, eto idibo ati kika esi ibo ni wọn se lati gbe lẹyin alatako oun, Senatọ Ademọla Adeleke.

Adeoti, kede igbesẹ rẹ naa lẹyin ti ọkan lara awọn ti wọn dijọ dije, tii tun se olori osisẹ lọọfisi gomina nipinlẹ Ọsun, Alhaji Gboyega Oyetọla, jawe olubori ninu ibo naa.

Nigba to n bawọn akọrioyin sọ̀rọ nilu Osogbo, Adeoti, ẹni ti amugbalẹgbẹ rẹ feto iroyin, Kayọde Agbaje soju fun ni awada kẹri-kẹri lasan ni eto idibo abẹnu to waye lọjọ ẹti naa, eyi ti ko se afihan ifẹ ọkan awọn asoju to wa nibẹ.

Amugbalẹgbẹ rẹ feto iroyin naa ni " Akọwe ijba yoo papa du ipo gomina sugbọn emi ko lee sọ abẹ asia ẹgbẹ ti yoo ti dije fun ipo naa."

Image copyright @MoshoodAdeoti
Àkọlé àwòrán Atẹjade kan ti Adeoti fi ransẹ si wọọdu idibo rẹ, tii se Wọọdu kejila, nijọba ibilẹ Iwo, fihan pe o ti fi ẹgbẹ oselu APC silẹ.

Wayi o, atẹjade kan ti Adeoti fi ransẹ si wọọdu idibo rẹ, tii se Wọọdu kejila, nijọba ibilẹ Iwo, fihan pe o ti fi ẹgbẹ oselu APC silẹ.

Ninu atẹjade naa si lo ti n dupẹ lọwọ gbogbo awọn alatilẹyin rẹ, to dibo fun, to si tun n jẹjẹ pe oun setan lati sisẹ fun ilọsiwaju ipinlẹ Ọsun ni ipokipo ti oun ba ba ara oun.