Ìsẹ̀lẹ̀ Boko Haram: Mọ́sálásí ni aso àdó ikú mọ́ra ti sọsẹ́

Ara awọn eeyan to ti fara gba ninu isẹlẹ ado oloro lati ọwọ Boko Haram lati ẹyin wa Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn eeyan ti isẹlẹ naa soju wọn ni ko din ni eeyan mẹjọ to se agbako iku ojiji naa nigbati awọn marun miran farapa.

Eeyan mẹjọ mii tun ti tẹri gbasọ lati ipasẹ ado iku Boko Haramni abule Konduga nipinlẹ Borno.

Idaji ọjọ Aje, ni deede aago marun kọja isẹju mẹẹdogun aarọ ni isẹlẹ naa waye nigbati aso ado iku mọra gbẹmi ẹni kan rin wọ inu mọsalasi lasiko irun idaji, to si yin ado oloro to wa lara rẹ.

Awọn eeyan ti isẹlẹ naa soju wọn ni ko din ni eeyan mẹjọ to se agbako iku ojiji naa nigbati awọn marun miran farapa.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Mọ́sálásí ni aso àdó ikú mọ́ra náà ti sọsẹ́

Meje ninu awọn eeyan yii lo gbẹmi mi ninu mọsalasi nigbati ẹni kan yoku ku loju ọna ile iwosan ti wọn n gbe lọ fun itọju.