Ọsun Decides: Charlie Boy ni ọ̀pọ̀ àìda ló wáyé lásìkò ìbò Ọ̀sun

Charlie Boy n sọrọ nibi iwọde

Gbajugbaja onkọrin takasufe nni, Charles Oputa ti ọpọ mọ si Charly Boy ti pe fun iwadii to jinlẹ lori bi eto idibo gomina ipinlẹ Ọsun to kọja ṣe lọ.

Charlie boy sọrọ yii nigba to darapọ mọ awọn ajafẹtọ ẹni miiran nibi apero kan ni ilu Osogbo.

O ni bi orileede Naijiria ko ba fẹ fi awokọṣe buruku lori ibo rira, didun mọhuru mọ oludibo ati magomago lasiko idibo lelẹ, afi ki awọn alasẹ ti ọrọ kan o yara tete ṣe iwadii to kunna lori bi isu ṣe ku, ti ọbẹ sí bẹẹ lasiko idibo naa.Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Jide Kosọkọ: Isẹ́ tíátà yóò gòkè tíjọba bá gbówó kalẹ̀ láti seré

Ni ọjọ Isẹgun ni ẹni ti ajọ INEC Kede pe o bori ninu idibo sipo gomina ni ipinlẹ Ọsun, eyi to waye ni osu kẹsan ọdun 2018, iyẹn Ọgbẹni Gboyega Oyetọla yoo máa tẹwọ gba ọpa aṣẹ gomina lọwọ Rauf Aregbesola, to ti di ipo naa mu fún ọdun mẹjọ.

Lara awọn ohun ti awọn ajafẹtọ naa salaye gẹgẹ bii aleebu ara idibo naa ni, ṣiṣe segesege awọn ẹrọ ti n yẹ kaadi oludibo wo, didun mọhuru mọ awọn akọroyin, pẹlu ohun ti wọn pe ni àìsí ootọ awọn oṣiṣẹ eleto idibo lasiko ti ibo naa waye.

Charlie Boy ni ojuse awọn ọmọ orilẹede yìí ni lati fi eto rere lelẹ fawọn iran ti o n bọ nipa eto idibo ti yoo ṣafihan ifẹ araalu ni tootọ.

Bẹẹ lo ni asiko idakẹ jẹẹ fún àwọn ọmọ orilẹede Naijiria ti to gẹẹ, yoo si dara kí wọn dìde láti tako eru lasiko idibo.

O wá rọ awọn ọdọ lati dide ja fun agbekalẹ eto iṣejọba tiwantiwa ti ko lẹjanbakan ninu, eto idari to see fi ọkan tan ati idajọ ododo fun mutumuwa, ki Naijiria lee tẹ siwaju.

Awọn ajafẹtọ miiran to sọrọ nibi eto naa ni Dare Ariyo lati ajọ Democracy and Good governance ati Festus Ojewumi lati ibudo to wa fun eto idajọ ododo ati ipẹtu saawọ.

Awọn yoku ni Festus Ojewunmi ati Wole Oladapo lati Virtues Restorative Justice Initiative.

Awọn ajafẹtọ naa ni, eto idibo gomina to waye ni ipinlẹ Ọsun jìnnà sí ìlànà aatẹle fún idibo lagbaye ti won sì ke sí ẹka isedajo lati fi oju tó tọ wo awọn ẹhonu to ba tipasẹ idibo naa jade sí ọdọ wọn.

Awọn ẹgbẹ oṣelu to wa nibi apero naa pẹlu ko sai rọ àwọn orileede agbaye lati mase kọpakọ si bi eto idibo àpapọ ọdun 2019 yóò ṣe lọ lorileede Naijiria.

Ìwọ́de, ìkọ̀wéfipò sílẹ̀, gbode lori ìdìbò abẹ́lé l‘Ọsun

Ìdìbò abẹnu ipinle Osun to waye lopin ọse, kángun kángun kángun,o kọ, ko ríbi kángun sí

Bi àwọn alatilẹyin ọgbẹni Akin Ogunbiyi tó fidi rẹmi nínú ìdìbò abẹnu ẹgbẹ òṣèlú PDP nipinlẹ Osun ṣé n wọde ni Olú ilé ẹgbẹ wọn nílu Òṣogbo lakowe osise ijọba ipinle Osun,Moshood Adeoti kowe fi APC sile.

Koda, Ọgbẹni Adeoti ti yan ẹgbẹ oselu ADP lẹbi tuntun ti o si ti kede idarapọmọ ẹgbẹ naa.

Adeoti ní aiṣedeede nínú ìdìbò abẹnu APC ló sún òun débi a n kowefiposilẹ àti wí pé òun ṣetan láti dije ipò Gómìnà nínú ìdìbò tó n bọ lónà lábé àsìá ẹgbẹ ADP.

Àkọlé àwòrán,

Toun ti ijakule idibo abẹnu APC,Moshood Adeoti tẹsiwaju ipinu rẹ lati di Gomina ipinlẹ Osun

Bákannáà lọmọ ṣori lọdọ awọn alatilẹyin ọgbẹni Akin Ogunbiyi ti wọn ṣe iwode lọ sí ilé ẹgbẹ PDP losogbo.

Wọn ní àwọn n ṣé iwọde náà láti fi ehonu hàn lórí àbájáde èsì ìdìbò abẹnu ẹgbẹ òṣèlú PDP to waye lopin ọsẹ to kọjá.

Wọn ní àwọn lòdì sí àbájáde ìdìbò náà èyí tí Seneto Ademola Adeleke jáwé olú bori.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé àwòrán,

Nisẹ ni awọn alatileyin Ogunbiyi fariga pẹ oun lo jawe olubori ninu idibo abẹnu to waye lopin ọsẹ

Àwọn alatilẹyin Akin Ogunbiyi ní, ti ẹgbẹ ba tẹsiwaju láti fà Ademola Adeleke kalẹ gẹgẹ bí Oludije ẹgbẹ PDP nínú ìdìbò Gómìnà ti yoo waye loṣù kẹsán, o ṣé ṣé kí ẹgbẹ náà padanu ipò Gómìnà.

Ṣáájú ní Akin Ogunbiyi ti tapa sí àbájáde ìdìbò abẹnu naa eyi to wáyé lópin ọsẹ nílu Òṣogbo.