PDP Ogun: Ilé ẹjọ́ dájọ́ àre fún Buruji Kashamu àti Adebayo Dayo

Aworan Seneto Buruji Kashamu

Oríṣun àwòrán, Sen_Kashamu

Àkọlé àwòrán,

Sẹneto Buruji Kashamu

Ile ẹjọ giga kan nilu Abuja ti fagile aṣẹ ẹgbẹ oselu Peoples Democratic Party, PDP to le Sẹnẹto Buruji Kashamu ati alaga ẹgbẹ nipinlẹ Ogun kuro ninu ẹgbẹ.

Ninu idajọ to waye lọjọru ti se ọjọ kẹ́wa osu kẹwa,adajọ Vanlentine Ashi ni igbese ẹgbẹ naa lati le Kashamu ati Dayo kuro ninu ẹgbẹ lodi sofin ti o si jẹ iwa aibikita fun aṣẹ ti ile ẹjọ ti saaju paa ki wọn ma se nnkankan lori ọr naa to wa ni iwaju ile ẹjọ.

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK/Senator-Buruji-Kashamu

Àkọlé àwòrán,

Aworan Seneto Buruji Kashamu

Lọjọ kẹtalelogun oṣu keje ni ẹgbẹ òṣèlú PDP ni kí Senetọ Buruji Kashamu kẹru rẹ kuro ninu ẹgbẹ awọn.

Asẹ yi waye lẹyin ipade gbogbogbòò ẹgbẹ PDP nibi ti ìgbìmò alákòóso ẹgbẹ ti pàṣẹ kí Seneto Kashamu Buruji àti àwọn mẹrin mí kuro ninu ẹgbẹ oselu PDP nipinlẹ Ogun.

Akọ̀wé ẹgbẹ́ òsèlú PDP, Ọ̀gbẹ́ni Kola Ologbondiyan lo lede oro yi loju opo Twitter ẹgbẹ naa.

Awọn mẹrin ti ọrọ naa kan ni Ogbẹni Samiu Sodipo,Bayo Adebayo aati asoju Segun Seriki.

Bakanna ni o so wi pe ẹgbẹ fasẹ si ki ẹka ẹgbẹ́ PDP ni ipinlẹ Ekiti tako ẹsi idibo Gomina ipinlẹ Ekiti to waye laarin asiko yi ni ile ẹjọ

Ìgbìmò alákòóso ẹgbẹ PDP tun fọwọ si adehun ti ẹgbẹ naa se pẹlu awọn ẹgbẹ oselu mii.

Wọn ni awọn yoo sapa lati ri wi pe gbogbo ẹgbẹ to jijo towo bọ adehun se aseyọri.

Sugbọn aṣẹ kuro ninu ẹgbẹ yi ko tẹ Sẹnẹtọ Buruiji Kashamu ati Alaga ẹgbẹ Adebayo Dayo lọrun ti wọn si pe ẹgbẹ sẹjọ ninu iwe ipẹjọ M/8696/2018, ti agbẹjọro wọn Charles Ndukwe fi tapa si aṣẹ kuro ninu ẹgbẹ wa yii.

Awijare wọn ni pe ẹgbẹ gbe igbesẹ naa nigba ti ọrọ naa si wa ni iwaju ile ẹjọ