Iná sọ ní Ilééṣẹ́ ijọba Ipinlẹ Osun

Ileeṣẹ Ipinle Osun

Ìròyìn ti fi han pe ina ti mu apa kan ọfiisi Gomina Ipinlẹ Osun, Rauf Aregbeṣọla, ni Oṣogbo.

Akọroyin wa to lọ s'ibi iṣẹlẹ naa wipe ni kete ti ina naa bẹrẹ ni awọn panapana b'omi pa ina naa. A gbọ pe ina naa bẹrẹ ni bii agogo marun.

Kọmiṣọna fun Eto Iroyin Adelani Baderinwa ni ina ijọba to sọ lojiji lati ara ẹrọ amule tutu lo fa iṣẹlẹ naa, ṣugbọn Aregbesọla ko si nile ni akoko naa.

Àwọn ti iṣẹ̀lẹ̀ naa ṣoju wọn ni ilẹkun ofiisi gomina ko ṣee ṣi nigba ti ina naa n jo lọwọ.

Baderinwa wipe ko si iwe kankan tabi irin iṣẹ ti ina naa bajẹ.

O ni, "Ọfiisi gomina nikan ni ina naa mu. Ko de awọn ofiisi to ku."