Oyedepo: Ẹni tó bá ń sàánú àwọn apànìyàn, kò ní mú 2018 jẹ

Oyedepo ni ọdun yii ko ni lọ lai jẹ pe Ọlọrun bẹ awọn eeyan to n gbẹmi awọn ọmọ orilẹ-ede yii wo
Olori ijọ Living Faith, ti wọn n pe ni Winners Chapel, Bisọọ́bu David Oyedepo ti fewe ọmọ mọ gbogbo awọn to n gbẹmi alaisẹ ni orilẹ-ede yii leti pe, ọjọ ẹsan wọn sunmọ etile, ti ilẹ yoo mọ ba osika wọn.
Oyedepo kede ọrọ yii lasiko iwaasu to se nibi isin ọjọ isinmi to waye ninu olu ijọ Winners to wa ni Ọta, nipinlẹ Ogun.
Gẹgẹ bo ti wi, ọdun yii ko ni lọ lai jẹ pe Ọlọrun bẹ awọn eeyan to n gbẹmi awọn ọmọ orilẹ-ede yii wo, to fi mọ awọn eeyan to n se atilẹyin fun wọn, tabi awọn to n saanu fun awọn apaniyan.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ọrẹ Falọmọ: Buhari yóò rí ìbò Yorùbá gbà ju Atiku, Ọbasanjọ lọ
Nigba to n gbarata lori isẹlẹ ipaniyan to waye ni ipinlẹ Benue laipẹ yii, nibi ti ọpọ ẹmi awọn araalu ti bọ, olori ijọ Winners lagbaye ni, o dabi ẹni pe ẹmi eeyan ko tiẹ wa jọ awọn apaniyan yii loju mọ, ti wọn ko si bikita mọ rara lati da ẹmi awọn eeyan legbodo.
"Emi ko ri iru isẹlẹ ipaniyan bi eyi ri, ti awọn eeyan n sare kiri, ti ọpọ wọn si n subu lulẹ, ti wọn n ku. O si yẹ ko ye wa pe gbogbo ẹmi lo jẹ ti Ọlọrun, to fi mọ ẹmi awn ẹranko, ti Ọlọrun si ti setan lati gba ẹsan lara ẹnikẹni to ba da ẹmi alaisẹ legbodo, ki ọdun yii to pari."
Oyedepo, ẹni ti iwaasu rẹ kun fun ire fawọn olujọsin rẹ, ati egun lori awọn ẹni apaniyan ni Naijiria, tun gegun pe ẹnikẹni to ba ni oun yoo pa eniyan ko to de ipo oselu, ko ni de ori ipo naa laelae.
Oyedepo ni o dabi ẹni pe ẹmi eeyan ko tiẹ wa jọ awọn apaniyan yii loju mọ, ti wọn ko si bikita mọ rara lati da ẹmi awọn eeyan legbodo.
Nigba to n tako iroyin kan to ni o n gba owo lọwọ awọn oloselu, Oyedepo ni oun ko gba kọbọ ri lọwọ oludije kankan ko to de ipo, ti oun ko si setan lati gba owo lọwọ oloselu kankan.
O fikun pe alaafia orilẹ-ede yii lo jẹ oun logun, eyi ti oun n tiraka fun ni gbogbo igba, bẹẹ si ni wolii Ọlọrun alaaye ni oun bi o tilẹ pe awọn woli eke wa, to fara jọ woli Ọlọrun.
Oyedepo tun rọ ojo epe sori awọn eeyan to n ti awọn apaniyan lẹyin pe, egun ati ibi to n bẹ lori awọn apaniyan naa ni yoo jẹ ipin tiwọn naa.
Oyedepo ni oun ko gba kọbọ ri lọwọ oludije kankan ko to de ipo, ti oun ko si setan lati gba owo lọwọ oloselu kankan.
"O da mi loju pe awọn alasẹ Naijiria ko lee sọ pe awọn ko ti awọn apaniyan lẹyin nitori gbogbo awọn eeyan tawọn agbofinro mu pe wọn n pa eniyan, ni ijọba ti tu silẹ patapata."
"Bawo ni wọn se lee maa gba ẹmi awọn ọmọ ilẹ yii ni gbogbo igba, ti a ko si tii ri ẹnikẹni mu lati fi jofin. Koda, ẹni tawọn agbofinro mu pe o pa iyawo oniwaasu kan ni ijọ Deeper Life, lo ti gba idande kuro lahamọ, ti wọn si tun dana sun ọpọ sọọsi lorilẹ-ede yii."
Oyedepo wa leri leka pe, laipẹ ni oun yoo kede iye sọọsi ti wọn ti sọ ina si ni orilẹ-ede yii.
Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ìkọlù àwọn Fulani Darandaran ti mún ọ̀ps ẹ̀mí lọ
Bakan naa, Olori ijọ Living Faith, ti wọn n pe ni Winners Chapel, Bisọọ́bu David Oyedepo ti kepe Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari, lati kọwe fipo silẹ lori ọrọ awọn Fulani darandaran ti wọn n fẹmi awọn eeyan ṣofo.
Bisọbu Oyedepo lo jẹ ojiṣẹ Ọlọrun kẹta, ti yoo rọ Aarẹ Buhari lati kọwe fipo silẹ lẹyin ti bisọọbu agba fun Ijọ Aguda l'Abuja, John Cardinal Onaiyekan, ati akẹẹgbẹ rẹ tẹlẹ nipinlẹ Eko, Cardinal Anthony Olubunmi Okogi, sọ fun Aarẹ Buhari lati fipo silẹ lẹyin to kuna lati daabo bo awọn ọmọ Naijiria.
Oyedepo sọ pe fifi ẹmi awọn alaiṣẹ Kristẹni ṣofo, papa julọ laarin gbungbun orilẹede Naijiria ti to gẹẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
O fi kun ọrọ rẹ pe, kin lode ti awọn Fulani darandaran fi n kọlu awujọ awọn ọmọlẹyin Kristi nikan, ti ọwọ sinkin ofin ko si mu wọn.
Ojiṣẹ Ọlọrun naa woye pe, awọn alaṣẹ ijọba lo n tiwọn lẹyin, bibẹẹkọ wọn o ba ti dẹkun ipaniyan.