Saraki: Ète láti fi ipá mú mi dúró ní APC yóò já s'ásán

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌlọpaa di ẹnu ọna ile Saraki pa

Aarẹ ile aṣofin agba Naijiria, Bukọla Saraki ti fesi si bi ileeṣẹ ọlọpa ṣe ni ko wa sọ nkan to mọ lori idigunjale kan to waye nilu Ọffa laipẹ yii.

Saraki ninu ọrọ kan to fi si oju opo Twitter rẹ ni, ileeṣẹ ọlọpa ti fi ọwọ́ oṣelu mu ọrọ idigunjale naa.

Ati pe, ''gbogbo igbesẹ naa dalori ati fi tipa-tipa mu oun ati awọn alatilẹyin oun duro ninu ẹgbẹ to n fi ẹsun ọdaran kan ni lọna ti ko bofin mu.''

Ṣaaju ni ileesẹ ọlọpaa ni Naijiria kọ lẹta si Saraki pe ko wa si olu ileeṣẹ wọn laago mẹjọ aarọ ọjọ Iṣẹgun, ko too di pe wọn fi ọkọ wọn dí oju ọna mọ ọ, ni deede aago mẹjọ aarọ oni.

Fidio bawọn ọlọpaa se sẹburu Saraki lati mase kọja lo wa loke yii.

Bẹẹ ba gbagbe, igba keji ree ti ileesẹ ọlọpaa pe Saraki lati yọju si awọn lori ọrọ idigunjale ilu Ọffa to waye laipẹ yii, amọ iwe ni Saraki kọ si wọn lati fesi pada, ki wọn to tun ransẹ pee lẹẹkeji.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Image copyright @Gidi_Traffic
Àkọlé àwòrán Ọpọ eeyan si lo ti n fi ikede naa soju opo ikansira ẹni wọn lori ayelujara.

Àsìkò tó ń lọ síléesẹ́ ọlọ́pàá lati lọ jẹ ipe ọga agba ọlọpaa to ransẹ pee lori ọrọ idigunjale Ọfaa, ni wọ́n sẹ́bùrú rẹ̀.

Image copyright @MrBanksOmisore
Àkọlé àwòrán Àsìkò tó ń lọ síléesẹ́ ọlọ́pàá ni wọ́n sẹ́bùrú rẹ̀.
Image copyright @Gidi_Traffic
Àkọlé àwòrán Ikorita Lake Chad nilu Abuja ni awọn ọlọpa ti sena mọ aarẹ ile asofin agba naa.

Ikede kan ti amugbalẹgbẹ aarẹ ile asofin agba, Senator bukọla Saraki fọrọ ibasepọ ilẹ okeere, ati isẹ nla-nla, Bamikọle Banks Omisore, fisita loju opo twitter rẹ ni ikorita Lake Chad nilu Abuja ni awọn ọlọpa ti sena mọ aarẹ ile asofin agba naa.

Ọpọ eeyan si lo ti n fi ikede naa soju opo ikansira ẹni wọn lori ayelujara, bẹẹ ni wọn n sọ ero wọn nipa isẹlẹ naa.

Lero ti @ogundamisi, o ni ko ba dara ki ileesẹ ọlọpaa faaye gba Saraki ko yọju si wọn na, ki wọn to maa lọ dena dee.

Rosanwo, @rosanwo naa ni iwa ọjaju si eto isejọba alagbada ni lati lo iwa ipa maa fi di ẹka isejọba lọwọ lati se is wọn.