Afárá 3rd Mainland: Ìjọba ṣí afárá lẹ́yìn àtúnṣe

Àwọn ọlọ́pàá lórí afárá 3rd Mainland ní ìlú Eko

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Iṣẹ́ àtúnṣe ti parí lórí afárá 3rd Mainland ní ìlú Eko

Ijọba ipinlẹ Eko ti kede pe afárá 3rd Mainland si erekusu ile Eko ti wọn ti pa lalẹ Ọjọbọ ti di ṣiṣi bayii.

Agogo marun-un irọlẹ ọjọ Aiku ni afara naa di ṣiṣi pada fun lilo.

Àkọlé àwòrán,

Afárá 3rd Mainland: Ìjọba ṣí afárá lẹ́yìn àtúnṣe

Kọmisọna fun igbokegbodo ọkọ nipinlẹ Eko, Ọmọwe Taiwo Salaam fidi rẹ mulẹ pe igbesẹ lati ṣi afara naa saaju igba ti wọn fẹẹ ṣi waye lẹyin ti wọn ti pari iṣẹ atunṣe ti wọn se lori afara naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Ọdún kan lẹ́yìn ogun musulumi Rohingya, ìbànújẹ̀ dorí àgbà kodò

Àkọlé fídíò,

'Mi o fẹẹkan ni mo fẹ dupo aarẹ'

Ẹ̀wẹ̀, akọ̀ròyìn wa tó ṣe abẹwo kaakiri erekusu ilu Eko jabọ pe wámúwámú ni àwon òṣìṣẹ́ agbófinró dúró láti mójútó ìgbòkègbodò ọkọ̀ nigba ti afara naa wa ni titi pa.

Àkọlé àwòrán,

àwon òṣìṣẹ́ agbófinró

Owó ọkọ̀ di gọbọi nígbà tí wọ́nti afara 3rd Mainland

Awakọ ni oju ọna afara third mainland ni ilu Eko, Ọlamilekan Rafiu ti sọ wi pe gbogbo eniyan to wa ni ilu Eko ni yoo faragba ninu igbese ijọba ipinlẹ Eko ati ijọba apapọ lati ti afara kẹta to wa ni ilu Eko.

Rafiu nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ wi pe igbese naa ku die kaato nitori ijọba ko gbe igbese to yege lati yanju isoro ọna apapa ti awọn ọkọ nlanla ma n pejọ pọ si ni oju ọna.

Ninu ọrọ rẹ, o fi kun un wi pe o di dandan ki awọn gbe owo le owo ọkọ nitori inira sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ yoo kọja agbara wọn.

Àkọlé fídíò,

Awakọ̀ 3rd Mainland Bridge: Ìjọba ko yanjú súnkẹrẹ fàkẹrẹ ọ̀nà Apapa

Wọn ti kọkọ dájọ titi 3rd mainland tẹ́lẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Idi ti wọn fi sun ọjọ ti wọn yoo ti afara naa si iwaju niise pẹlu igbiyanju ijọba ipinlẹ Eko lati mu idiwọ ati ipara ti yoo jẹ fun awọn ara ilu kuro lasiko naa

Ijọba apapọ ti sun ọjọ mẹta ti wọn fẹ fi se atunse afara "Third mainland bridge" lati ọjọ kẹtadinlọgbọn si ọgbọnjọ Osu yii, si ọjọ kẹrinlelogun si ọjọ kẹrindinlọgbọn, Osu kẹjọ ọdun 2018.

Minisita fun ọrọ isẹ ode, ọrọ ilẹ ati ilegbe, Arakunrin Babatunde Fashola lo se ikede iyipada ọjọ atunse afara naa ninu atẹjade kan to fun awọn oniroyin.

Fashola ni, idi ti wọn fi sun ọjọ ti wọn yoo ti afara naa si iwaju, nii se pẹlu igbiyanju ijọba ipinlẹ Eko lati mu idiwọ ati ipalara ti yoo jẹ fun awọn ara ilu kuro lasiko naa.

Minisita naa fikun wipe, Ijọba apapọ tun pasẹ fun awọn ọkọ nla nla lati dari si papakọ to gba ọọdunrun ọkọ, ti wọn se lati dẹkun sunkẹrẹ ọkọ ni oju ọna marọse Oshodi si Apapa.