PDP: Kashamu ti gba ìwé nílé ẹjọ́ láti gbé àwọn asaájú wa

Buruji Kashamu Image copyright @Sen_Kashamu
Àkọlé àwòrán PDP ni ijọba apapọ ati Kashamu ti n dete lati fi iwe asẹ ile ẹjọ gbe awọn asaaju ẹgbẹ oselu naa.

Wahala to n waye laarin ẹgbẹ oselu PDP ati sẹnatọ kan lati ipinlẹ Ogun, Buruji Kashamu, ko tii jẹ rodo, lọ ree mu omi o, lẹyin ti awọn alasẹ ẹgbẹ PDP le Kashamu kuro ninu ẹgbẹ wọn.

Idi ni pe awọn asaaju ẹgbẹ oselu PDP ti fi igbe bọnu lana pe ijọba apapọ ati Kashamu ti n dete lati fi iwe asẹ ile ẹjọ gbe awọn asaaju ẹgbẹ oselu naa.

Akọwe ipolongo fẹgbẹ oselu PDP, Kọla Ọlọgbọndiyan lo fi ikede naa sita lasiko to n bawọn akọroyin sọrọ nilu Abuja, pẹlu afikun pe Kashamu n gbe igbesẹ naa nitori igbesẹ ti PDP gbe lati juwe ọna ile fun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWùnmí Toríọlá: Toyin Abraham kìí se ọ̀gá mi nínú tíátà

Ọ́lọgbọndiyan ni "Awa la ni ẹgbẹ wa, ti wọn si yan wa lati maa se akoso rẹ nibamu pẹlu ofin orilẹ-ede Naijiria. Bi a si se n tukọ ẹgbẹ oselu PDP wa nibamu pẹlu ofin naa, to fi mọ awọn igbesẹ taa n gbe ati ipinnu ti a n se. Nitori naa, gbogbo igbesẹ kigbesẹ ti ẹnikẹni ba gbe lati ba ẹgbẹ naa laa tako pata-pata."

Image copyright @PDP
Àkọlé àwòrán PDP wa rọ awọn ọmọ ẹgbẹ oselu PDP lati mase foya

Ọlọgbọndiyan, ẹni to se apejuwe igbesẹ bi ijọba apapọ lati dena de Saraki ati Ekweremadu, ti wọn jẹ asaaju ile asofin apapọ, bii iwa ọyaju ati idunkoko mọni lati ọdọ ijọba ẹgbẹ oselu APC ati aarẹ Muhammadu Buhari.

O wa rọ awọn ọmọ ẹgbẹ oselu PDP lati mase foya nitori iwa idunkoko mọni naa, to si tun n rọ awọn ololufẹ eto iselu ijọba tiwa n tiwa kaakiri agbaye lati dide tako iru iwa aidaa yii.