NFF: Àjọ NFF ní kí Salisu lọ rọ́kún nílé f'ọ́dún kan

NFF: Àjọ NFF ní kí Salisu lọ rọ́kún nílé f'ọ́dún kan

Ajọ to n ri si ere bọọlu lorilẹede Naijiria NFF ti sọ fun akọnimọọgba ikọ Super Eagles Salisu Yusuf pe ko lọ rọkun nile fun ọdun kan lori ẹsun owo riba.

Ẹka ajọ NFF to n ri si iwuwa si sọ pe Yusuf jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an pe o gba ẹgbẹrun kan owo dọla abẹtẹlẹ gẹgẹ bi fidio ti akọroyin idakọkọ ọmọ ilẹ Ghana to fun BBC Arameyaw Anas gbe jade ṣe fihan.

Ẹka naa tun paṣẹ fun Salisu lati san ẹgbẹrun marun-un owo dọla gẹgẹ bi owo itanran laarin oṣu mẹta si ajọ NFF.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Fidio ṣe afihan ibi ti Salisu ti tẹwọ gba owo naa.

Wọn tun ṣeleri lati san idamẹẹdogun owo adehun iṣẹ fun Salisu ti ikọ lati oke okun ba ra agbabọọlu naa ninu fidio ọhun.

Iṣẹlẹ naa waye nigba ti idije ife ẹyẹ 2017 WAFU n lọ lọwọ lorilẹede Ghana nibi ti Ghana ti fagba han Naijiria ami ayo mẹrin sẹyọkan ninu aṣekagba idije naa.