Red Cross: Irọ́ ni pé á ń duna-dura pẹ̀lú Boko Haram

Awọn ọmọ ẹgbẹ Red Cross Image copyright @nrc_ng
Àkọlé àwòrán Iduna-dura lu Boko Haram yoo pagidina ohun ti ẹgbẹ Red Cross duro fun

Agbarijọpọ ẹgbẹ alagbelebu pupa l'agbaye (Red Cross) ti kede pe, oun kii duna-dura pẹlu ikọ adunkooko mọni kankan lori awọn ti ikọ naa ji gbe.

Agbẹnusọ fun ẹgbẹ naa, Alexsandra Matijevic Mosimann, to fi ikede naa sita ni, ko sootọ kankan ninu awọn iroyin kan to n jade pe, oun ba ikọ Boko Haram sọrọ lati da awọn to mu si ahamọ silẹ.

O ni ṣiṣe bẹẹ yoo pagidina ohun ti ẹgbẹ Red Cross duro fun, eyi ti i ṣe aiṣègbè tabi fifi ara ti ẹnikẹni.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBáwo lo se gbọ́ èdè Yorùbá sí ?

Ọpọlọpọ eniyan ni ikọ agbesunmọmi Boko Haram ti ji gbe lapa Iwọ-Oorun Ariwa orilẹ-ede Naijiria, ti eyi si n mu ki orisirisi ajọ alaanu nilẹ okeere ati l'abẹle, to fi mọ awọn ẹlẹyinju aanu, maa pese iranlọwọ fun awọn ti ikọlu Boko Haram ti sọ di alainile lori.

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Red Cross ni ko sootọ kankan ninu awọn iroyin kan to n jade pe, oun ba ikọ Boko Haram sọrọ

ICRC ti wa ni ohun kan ti oun le ṣe gẹgẹ bi iranlọwọ ni lati pese eto irinna fun awọn ti wọn ji gbe pada si ile wọn.