Ortom: APC ko ṣe bi ẹni pe ọrọ awọn ara Benue jẹ wọn logun

Gomina Ipinlẹ Benue, Samuel Ortom

Oríṣun àwòrán, @OrtomSamuel/Twitter

Àkọlé àwòrán,

Agbẹnusọ Ortom ni APC ko ṣe gomina naa daadaa

Ẹ̀gbẹ́ òṣèlú All Progressive Congress, APC ti fèsì pé bí Gómìnà Samuel Ortom ṣe fi ẹgbẹ́ òṣèlú wọn sílẹ̀ jẹ́ èyí tó ya ni lẹ́nu.

APC ṣèránti akitiyan alága ẹgbẹ́ Adams Oshiomolẹ láti kojú àwọn ìkùnsínú kọ̀ọ̀kan tí Gómìnà ìpínlẹ̀ Benue mẹ́nu bà èyí tó ní ṣe pẹ̀lú òṣèlú abẹ́nú ní ìpínlẹ̀ Benue.

Lẹyin ọsẹ kan ti iroyin kọkọ kede pe, Gomina Ipinlẹ Benue, Samuel Ortom ti fẹ fi ẹgbẹ oṣelu APC silé lọ PDP, iroyin fi han pe o ti fẹgbẹ APC silẹ bayii.

Kọmisọna fun Iroyin ana ni ipinlẹ naa, Laurence Onoja lo kọkọ fi han fun BBC pe, ootọ ni iroyin naa. Lẹyin naa ni agbẹnusọ gomina naa, Terver Akase gbe atẹjade lori ipinnu naa sita.

A gbọ pe, Ortom funra rẹ sọ bẹẹ fun awọn alaga ijọba ibilẹ niipinlẹ naa ninu ipade kan to waye nile ijọba ni Markurdi.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Ìwádìí Anas: $1000 ni rìbá tí akọ́ni-mọ̀ọ́gbá Super Eagles gba

Akase ni, "Ẹgbẹ oṣelu APC ko ṣe daadaa si gomina (Ortom). APC ko ṣe bi ẹni pe ọrọ awọn ara Benue jẹ wọn logun, nitori naa ni awọn ọdọ ilu ṣe di ọna mọ gomina ni aarọ yii, ti wọn ni ko gbọdọ lọ ipade ipẹtu saawọ APC kan ti wọn gbe kalẹ ni Abuja. Wọn ni awọn ko fẹ ko duro si ẹgbẹ APC."

Kin lo de ti Ortom fi kuro ni APC

Nigba ti BBC beere boya gomina naa sa kuro ni APC nitori ẹsun pe ko le daabo bo ẹmi ati dukia awọn eniyan Benue ni, o ni ko ri bẹ, ati pe awọn oloṣelu ti ko fẹran rẹ ni wọn n parọ mọ.

Ipinnu na waye lẹyin ti a gbọ pe awọn ọdọ kan ni Makurdi di ọna mọ ọkọ rẹ nigba ti o fẹ rinrin ajo lati lọ ipade kan ni Abuja. Àwọn ọdọ naa tun yọ asia ẹgbẹ APC to wa lara ọkọ rẹ.

Oríṣun àwòrán, @OrtomSamuel/Twitter

Àkọlé àwòrán,

Awọn ọdọ ni Ortom ko gbọdọ lọ ipade Abuja

O ya ni lẹnu pe ni ọsẹ to kọja nigba ti gomina naa kọkọ fi han pe, oun fẹ fi ẹgbẹ APC silẹ, sugbọn to tun yi oju pada lati sọ pe ko ri bẹẹ.

Ortom ni gomina akọkọ ti yoo fi ẹgbẹ oselu APC silẹ

Oun ni gomina akọkọ ti o maa tẹle awọn aṣofin mẹ́tàléláàdọ́ta to fi ẹgbẹ APC silẹ lọ PDP lanaa.

Ortom ti ni ija pẹlu ijọba apapọ fun igba diẹ lori iku awọn ara ilu lọwọ awọn darandaran. Oṣu kinni ọdun yii ni awọn darandaran pa eniyan bii mẹtalelaadorin ni ipinlẹ naa. Ọpọlọpọ ni wọn ti pa pẹlu lati igba naa.