Ààrẹ Buhari: Ó ṣeéṣe kí o lè wọ reluwé lọ orílẹ̀èdè Benin láìpẹ́

Ọkọ oju irin laarin igboro ilu Eko

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Aarẹ Buhari ni laarin igba ti oun gba ọpa aṣẹ iṣejọba lọdun 2015 si asiko yii, fayawọ irẹsi ti dinku pẹlu ida aadọrun lorilẹede Naijiria

Aarẹ Buhari ati aarẹ Patrice Talon ti orilẹede Benin Republic ni oju opo irinna ọkọ reluwe laarin orilẹede Naijiria, Benin republic ati Niger Republic jẹ ohun ti ko yẹ ko pẹ pupọ ki o to di ohun.

Lasiko ti aarẹ Patrice Talon ti orilẹede Benin republic ṣe abẹwo si aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari nilu Abuja.

Aarẹ Buhari ni " igbesẹ to dara ni eyi ti o si ṣe pataki fun idagbasoke ọrọ aje" ti wọn yoo si tubọ gbe yẹwo daradara.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Orilẹede Naijiria pẹlu orilẹede Benin Republic ni fayawọ n ṣe akoba fun eto ọrọ aje ati eto abo

Bakan naa ni orilẹede Naijiria pẹlu orilẹede Benin Republic tu n gbe igbesẹ lati dẹkun fayawọ irẹsi ṣiṣe laarin aala orilẹede mejeeji.

Lara igbesẹ yii naa ni afẹnuko laarin orilẹede mejeeji lori agbekalẹ igbimọ kan ti yoo maa gbogun ti iwa fayawọ.

Lasiko abẹwo Aarẹ Patrice Talon si aarẹ Muhammadu Buhari naa ni wọn fi ẹnu ọrọ ọhun jo sibikan.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Buhari ni lara awọn akoba ti owo fayawọ n ṣe ni ti awọn ohun ija oloro ti wọn n ko wọ orilẹede Naijiria, to si n ṣe igbọwọ fun eto abo to mẹhẹ

Aarẹ Buhari ni laarin igba ti oun gba ọpa aṣẹ iṣejọba lọdun 2015 si asiko yii, fayawọ irẹsi ti dinku pẹlu ida aadọrun lorilẹede Naijiria.

Aarẹ fi kun un pe akoba ti gulegule awọn fayawọ n ṣe fun ilakaaka orilẹede Naijiria lati lee daa ẹnu ara rẹ bọ ni ti ounjẹ abẹle ko kere rara.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni lara awọn akoba ti owo fayawọ n ṣe ni ti awọn ohun ija oloro ti wọn n ko wọ orilẹede Naijiria, to si n ṣe igbọwọ fun eto abo to mẹhẹ.

Ninu ọrọ tirẹ, Aarẹ Patrice Talon ṣalaye pe aarun ti n ṣogoji nii ṣ'ọọdunrun ni ọrọ akoba fayawọ nitori bo ṣe n koba ọrọ aje Naijiria naa lo n koba ọrọ aje orilẹede Benin republic.