Àárẹ̀ wo ló mú kí Dino má yọjú sile ẹjọ́?

Aworan Sẹnẹtọ Dino Melaye Image copyright Dino Melaye/Facebook
Àkọlé àwòrán Ọrọ gbogbo kìí sé lórí alábahun Dino Melaye

Dino tún kọ̀ láti yọjú sílé ẹjọ́ nígbà kejì

Fún ìgbà ìkejì, Seneto to n sójú ẹkùn ìdìbò ila oòrùn Kogi, Dino Melaye, ti kùnà láti yọjú sile ẹjọ to n gbọ ẹjọ rẹ eleyi to da lè ẹsùn ṣisowo ìbon lọnà tí kò bá òfin mu.

Òun àti àwọn afẹsunkan méjì ní wọn fẹsun náà kan níwájú Adájọ.

Ṣáájú ní agbẹjọro Melaye ti beere fún isunsiwaju ẹjọ náà nítorí pé Dino ní àwọn kan fẹ ji òun gbe lójú ọnà Abuja si Lokoja.

Nígbà tí wọn pè fún igbejọ rẹ lójóóru n'isẹ ní agbẹjọro rẹ, Yemi Mohammed, ní ará Dino kò yá ni kò fi le yọjú sile ẹjọ.

Láti kín ọrọ rẹ lẹyìn, Mohammed fi ìwé nípa ìlera rẹ ṣòwò eleyi ti agbẹjọro fún ilé iṣẹ ọlọpaa ipinle Kogi kò lòdì sí.

Àwọn afẹsunkan méjì tó kù, Kabir Seidu àti Nuhu Salihu bẹbẹ fún ilé ẹjọ pé ki wọn gbà beeli awọn pẹlu awijare pe awon ko mo nipa ẹsùn tí wọn fi kan àwọn.

Adájọ Sulyman Abdallah dajọ isunsiwaju ẹjọ náà titi di ọjọ kokanlelogun níbi tí wọn yóò ti gbọ ẹjọ àwọn afẹsunkan méjì tó kù.

Ogunjọ, oṣù kẹsán ní wọn sun ẹjọ Seneto Dino Melaye sí.

Ohun ti awọn eeyan sọ nipaijinigbe Dino tẹlẹ

Image copyright @dino_melaye
Àkọlé àwòrán Ọjọ́ Kẹtadinlọgbọn, Osu Keje, ọdun yii ni Oluranlọwọ Dino Melaye sọ wi pe wọn jii gbe ni Gwagalada, Abuja.

Ọrọ ijinigbe Seneto Dino Melaye gbà ònà míràn yọ pẹlú bí o tí ṣé bẹnu àtẹ́ lù ilé iṣẹ ọlọ́pàá pe wọn parọ pé àbúrò òun kò fẹjo sun lagọ ọlọ́pàá.

Èsì yí to fí ṣọwọ lójú òpó Twitter rẹ jáde lẹyìn ìgbà tí o fi esi ọpẹ sita lori bí orí ṣé ko oun yọ lọwọ àwọn ajinigbe.

Dino faake kọri o ni aburo oun fẹjọ sun awọn ọlọ́pàá laarọ Ọjọbọ

Ti a ko ba gbagbe,Sẹnetọ Dino Melaye to n soju ẹkun idibo Iwọ- oorun Kogi, ti saaju kede pe oun ti jajabọ ni ọwọ awọn to ji oun gbe.

Oro naa to fi lede ni oju opo Twitter rẹ ni, ori lo ko oun yọ, lẹyin ti oun lo wakati mọkanla ninu aginju lẹyin ti wọn ji oun gbe.

Oluranlọwọ fun sẹnetọ Dino Melaye, Gideon Ayọdele nigba to n ba BBC sọrọ so pe ni ikorita Gwagwalada, ni ilu Abuja ni awọn agbebọn ti fẹ ji Dino gbe.

"Iro ojukoroju ni Sẹnẹtọ Dino Melaye n pa"

Awọ̀n ọmọ Naijiria fesi si oun ti Sẹnẹtọ Dino Melaye fi si oju opo rẹ wipe ori lo yọ oun ninu isẹlẹ ajinigbe ti oun ti lo wakati mọkanla ni inu igbo ki oun to rapala jade pada si ilu.

Wọn ni irọ lasan ni Dino n pa, ati wi pe ko si otitọ kankan ninu ọrọ rẹ, ti awọn miran si n fi se ẹlẹya.

Àkọlé àwòrán Ọjọbọ ọsẹ yii ni Oluranlọwọ fun sẹnetọ Dino Melaye, Gideon Ayọdele ni ikorita Gwagwalada, ni ilu Abuja ni awọn agbebọn pẹlu ọkọ ijọba ipinlẹ Kogi lo ji Dino gbe.

Amọ olulufẹ rẹ kan dupe pe o wa ni alaafia, ti o si rọ ọ lati gbe fidio jade ti yoo fihan wipe alaafia ni o wa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌ̀ṣọ́ Aṣọ Òkè ti kọjá lílo ìlẹ̀kẹ̀ níkan
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSMS alert: Wo ọ̀nà láti dẹ́kun jìbìtì lórí àṣùwọ̀n báǹkì rẹ