Osun elections: Ìdí tí Fatai Akinbade fi kúrò lẹ́gbẹ́ òṣèlú PDP l'Ọ́ṣun

Fatai Akinbade Image copyright facebook/fatai akinbade
Àkọlé àwòrán Fatai Akinbade kọ ni oloṣelu akọkọ ti yoo fi ẹgbẹ oṣelu rẹ silẹ lẹnu ọjọ mẹta yii nipinlẹ Ọṣun

Ọkan pataki lara awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ọṣun ni oloye Fatai Akinbade koda o wa lara awọn oludije mẹrin to kopa ninu idibo abẹnu lati yan oludije fun ipo gomina labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu PDP.

Fatai Akinbade ninu iwe to kọ lati fi ẹgbẹ oṣelu PDP silẹ ṣalaye pe abajade esi idibo abẹnu naa ninu eyi ti o ti ni ibo mejilelaadọta lo fa oun si irin lati fi ẹgbẹ oṣelu naa silẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Lẹyin ti mo ti rii pe o dabi ẹni pe awọn adari ẹgbẹ oṣelu yii ko fẹ mi mọ tabi pe wiwa ti mo wa lẹgbẹ yii n dooru mu wọn ni mo fi gbe igbesẹ yii. Ero mi lori awọn nnkan wọnyii wa fidi mulẹ lasiko idibo lati yan oludije fun ipo gomina eleyi ti o waye laipẹ yii."

Fatai Akinbade kọ ni oloṣelu akọkọ ti yoo fi ẹgbẹ oṣelu rẹ silẹ lẹyin eto idibo lati yan awọn oludije fun ipo gomina l'Ọṣun.

Àkọlé àwòrán Moshood Adeoti naa ti kọwe fi ẹgbẹ oṣelu APC silẹ lori ẹsun to fi ara jọ ti Akinbade, to si gba ẹgbẹ oṣelu APD lọ

Ṣaaju ni akọwe ijọba ipinlẹ naa tẹlẹ, Moshood Adeoti naa ti kọwe fi ẹgbẹ oṣelu APC silẹ lori ẹsun to fi ara jọ ti Akinbade, to si gba ẹgbẹ oṣelu APD lọ.

Awuyewuye n lọ lọwọ lori esi idibo abẹnu PDP pẹlu bi Akin Ogunbiyi to ṣe ipo keji ninu idibo ọhun ṣe ti n f'apa janu bayii pe ohun lo bori ninu idibo naa.