Àwòrán àwọn tó kù pẹ̀lú Buhari láàárín àwọn sẹ́nétọ̀ Nàìjíríà nìyí

Buhari pẹlu awọn Sẹnetọ to ku lẹgbẹ oṣelu APC

Oríṣun àwòrán, Nigeria presidency

Àkọlé àwòrán,

Buhari ti ki awọn to ya kuro lẹgbẹ oṣelu APC pe iwaju ti wọn doju kọ yoo dara.

Ṣe awọn agba bọ, wọn ni, kii buru titi ko maa ku ẹni kan mọ ni; ẹni ti yoo ku ni a ko mọ.

Asiko yii kii ṣe igba to dun fun ẹgbẹ oṣelu APC, paapaa julọ Aarẹ Muhammadu Buhari to jẹ olori ẹgbẹ oṣelu naa bayii.

Ko din ni sẹnetọ mejila to fi ẹgbẹ oṣelu APC silẹ pẹlu ọgọọrs awọn akẹgbẹ wọn nile aṣoju ṣofin pẹlu aṣofin ipinlẹ kaakiri.

Amọṣa ninu iji yii, awọn wọn ni wọn ṣẹku pẹlu Aarẹ Buhari bayii.

Oríṣun àwòrán, Bashir ahmad

Àkọlé àwòrán,

Aarẹ orileede Naijiria,Muhammadu Buhari ni oun ti sapa ti oun lati dẹkun bi awọn aṣòfin marundilogun to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC tẹle ṣe paarọ aye lọ si ẹgbẹ PDP

Oríṣun àwòrán, Nigeria Presidency

Oríṣun àwòrán, Nigeria presidency

Àkọlé àwòrán,

Igbesẹ awọn aṣofin to fi ẹgbẹ oṣelu APC silẹ ya ọpọlọpọ lẹnu

Oríṣun àwòrán, Nigeria presidency

Àkọlé àwòrán,

Aarẹ Buhari parowa si awọn ọmọ ẹgbẹ APC to ku ki wọn ma banujẹ lori iṣẹlẹ ọhun

Oríṣun àwòrán, Bashir ahmad

Àkọlé àwòrán,

Aarẹ ni igbesẹ awọn aṣòfin naa ko le ba nkan jẹ fun ẹgbẹ wọn bi idibo gbogbogbo 2019 ṣe n sunmọle

Oríṣun àwòrán, Bashir Ahmad

Àkọlé àwòrán,

Buhari sọ wipe oun yoo tẹsiwaju ninu iṣẹ oun pẹlu gbogbo awọn ọmọ ile igbimọ aṣòfin lalai fi ti ẹgbẹ ọṣelu wọn ṣe

Oríṣun àwòrán, Bashir ahmad

Àkọlé àwòrán,

Awọn aṣofin naa ya lọsi ẹgbẹ oṣelu PDP, ADC ati ẹgbẹ oṣelu miran

Oríṣun àwòrán, Bashir Ahmad

Àkọlé àwòrán,

Iyalẹnu ni ọrọ naa jẹ fun ọpọlọpọ onwoye ni Naijiria ati loke okun

Oríṣun àwòrán, Bashir ahmad

Àkọlé àwòrán,

Ẹgbẹ oṣelu APC ni awọn to ya kuro ninu ẹgbẹ oṣelu naa ko lee ṣe akoba fun ifẹsẹmulẹ ipinnu ẹgbẹ naa.