Àwọn òṣìṣẹ́ ilé iṣẹ́ ìròyìn NAN wọ́de lórí ìlànà iṣẹ́ tó mẹ́hẹ

Image copyright Abdulwahab
Àkọlé àwòrán Awọn oṣiṣẹ NAN ke si'jọba apapọ lati tete wa wọrọkọ fi ṣada lori amojuto igbayegbadun awọn oṣiṣẹ.

Awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ akoroyinjọ apapọ Naijiria, NAN gunle iyanṣẹlodi niwaaju olu ileeṣẹ naa nilu Abuja.

Kutukutu owurọ ọjọbọ lawọn oṣiṣẹ naa ti ya bo olu ileeṣẹ ọhun pẹlu awọn patako alakọle ti wọn kọ awọn ẹhonu wọn si.

Lara awọn ẹhonu ti awọn oṣiṣẹ naa n beere fun ni atunyẹwo ilana iṣẹ ni ileeṣẹ naa eleyi ti wọn ni wọn ni o ti di ogbo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀwọn oṣiṣẹ feyinti ni Osun ṣé iwọde

Bakannaa ni wọn tun beere fun sisan ẹgbẹrun marun owo irinsẹ fun awọn oṣiṣẹ, sisan ajẹẹlẹ owo ajẹmọnu igbega laarin ọdun 2012 si 2017 pẹlu adinku to waye lori ajẹẹlẹ owo ajẹmọnu igbega laarin ọdun 2014, 2015 ati 2016 atawọn nnkan miran.

Atẹjade kan ti awọn adari ẹgbẹ oṣiṣẹ iroyin, NUJ, ẹgbẹ oṣiṣẹ radio ati tiata, RATTAWU fi sita ṣalaye rẹ pegbogbo ilakaka awọn oṣiṣẹ nileeṣẹ naa lati ri pe irawọ rẹ ko wọmi ni aisi amojuto fawọn oṣiṣẹ nibẹ n bu omi pa.

Wọn wa ke si ijọba apapọ lati tete wa wọrọkọ fi ṣada lori amojuto igbayegbadun awọn oṣiṣẹ, alekun owo oṣu, ati ilana iṣẹ to tọna fun awọn oṣiṣẹ nibẹ.