Lunar Eclipse: Babalawo lo le sọ bí ire ni yóò já sí ní tàbí ibi

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOloye Ìdòwú Olukunle so pe babalawo lo le mo òun ti ọ̀sándòru yóò já sí fun ara ilu.

Ikéde ti awọn onímọ̀ sáyẹ́nsì fi síta pé ìṣẹlẹ ọ̀sándòru kàn yóò waye ti mu iriwisi wa lati ọdọ awọn onimo nipa Asa Yoruba.

Lasiko to ba n sẹlẹ, ojú òrun yoo pawọ dá ti awọ òṣùpá yóò sì ṣadede di pupa bí awọ ẹjẹ.

Ìṣẹlẹ yí tí awon oloyinbo n pe ni 'blood moon' yóò wáyé fún nnkán bi wakati kan ati ogójì iṣẹju le diẹ.

Àlàyé tí awọn onimo sayensi ṣe nipa iṣele naa ni wipe òṣùpá yóò gbà arin ojiji orilẹ ayé ta wa yi ati òrun koja,ojiji ti orun ba tàn sara òṣùpá ni yóò mú kí awọ rẹ pupa bí ẹjẹ.

Òun tí ifá sọ

'Irú ìṣẹlẹ bayi ki ṣéé túntún nilẹ Yoruba, kò ṣèṣe má wáyé.''

Ọrọ rẹ láti ẹnu Oloye Ìdòwú Olukunle ti ọ jẹ akoda awo ti ìjọba ibilẹ ọnà ará nílu Ibadan nigba ti wọn se alaye fún ilé iṣẹ BBC nipa ìṣẹlẹ òṣùpádeje tí yóò wáyé loní.

Image copyright SPL
Àkọlé àwòrán Ọ̀ṣùpádẹ̀jẹ̀

O ni awọn onimo sayẹnsi le mọ nípa ọjọ ti iru ìṣẹlẹ yí yóò wáyé ṣugbọn ''Babalawo lo le mo òun ti yóò gbẹyin rẹ.'

Fun ìdí èyí o so pe ''o yẹ kí àwọn aláṣẹ kesi Babalawo lati sọ 'boya ire ni yóò já sí ní tàbí ibi fun ara ilu'

Bakanaa ni alagba Ìdòwú ṣàlàyé pé ètùtù ní í gbẹyin irú ìṣẹlẹ bayii sugbọn pẹlu bi nnkan ti se ri lode oni, awọn eeyan ko ka ọrọ etutu sise kun mọ

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí:

Anfani de fun ọ lati lo internet lọfẹ

'Ọ̀jẹ̀lú ni àwọn tó ń fi APC sílẹ̀ fún PDP'

Níbo gaan ni Òṣùpádẹ̀jẹ̀ yóò ti ṣẹlẹ̀ lágbàyé?

Àwọn ibi tí ọ̀sándòru yìí yóò ti wáye ni Europe, ààrin gbùngbùn Ìlà Oòrùn, Africa, Australia Asia, South America àti ní UK láti nkan bíi agogo mẹ́sàán sí mẹ́wàá kọjá ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dógún alẹ́ káàkiri.

Lálẹ́ yii kan náà àt'àwọn ọjọ́ tó tẹ̀lé e ni yóò jẹ́ ìgbà tí Mars yóò sún mọ́ ayé jù láti ọdún 2003 tí yóò sì mọ́lẹ̀ bí ìràwọ̀ pupa níbi tí ojú ọ̀run ti mọ́.

Àkọlé àwòrán Àwòrán bí Ọ̀ṣùpádẹ̀jẹ̀ yóò ṣe wáyé

Kí ló dé tí ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀ṣùpádẹ̀jẹ̀ náà yóò pẹ́?

Òṣùpá yóò la àárin òjiji ayé kọjá lọ́gángán ibi tí òjiji náà ti fẹ̀ jù.

Òṣùpá yóò fara hàn pẹ̀lú àwọ̀ pupa nínú ọ̀ṣùpádẹ̀jẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí ìtànsán oòrùn yóò ṣe gba inú ayé kọjá fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Tim O'Brien ti ilé ìwé gíga fásitì Manchester sàlàyé pé eléyìí ni yóò jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀ṣùpádẹ̀jẹ̀ tó gùn jù ní ọ̀ọ̀rùndúnrún yìí.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ìṣẹ́lẹ̀ ọ̀sándòru ní Montevideo, Uruguay, ọdún 2014

Bákan náà, kò kàn ṣe kòńgẹ́ bí Mars yóò ṣe súnmọ́ ayé nìkan sùgbọ́n yóò jẹ́ pẹ̀lúu ohun tí ọ̀jọ̀gbọ́n ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí títòjáde àwọ́n òfurufú òkè tí wọ́n jẹ́ amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ òde ayé.

Èyí ni yóò jẹ́ ànfàni fún àwọ́n awòràwọ̀ láti rí Venus, Jupiter, Saturn àti Mars dáadáa.