Iléeṣẹ́ google gbé àǹfàní internet ọ̀fẹ́ wọ Eko

Aworan google Nigeria Image copyright Punchng
Àkọlé àwòrán Ileeṣẹ ikanni ayelujara, google ti gbe awọn ibudo lilo ayelujara lọfẹ wa si agbegbe marun nipinlẹ Eko

Anfani ti wa fun awọn ọmọ orilẹede Naijiria lati maa lo ikanni ayelujara, internet lọfẹ bayii nipinlẹ Eko.

Awọn ibudo mẹfa ni anfani yii sọkalẹ si nipinlẹ Eko, eleyi ti ko ni na ọ lowo ti ko si si gbede fun; iye to ba wu ọ, tabi ohun to ba wu ọ lo si lee fi gba lori ikanni ayelujara.

Ileeṣẹ ikanni ayelujara, google ti gbe awọn ibudo lilo ayelujara lọfẹ wa si agbegbe marun nipinlẹ Eko.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOsisẹ Fidelity Bank: Lati Osu Kẹwa, ọdun to kọja lati gba owo osu kẹhin.

Gẹgẹ bii awọn alaṣẹ ileeṣẹ naa ṣe sọ, awọn ibudo ti ifa yii gunlẹ si naa ni

  • The Palms shopping mall, Lekki
  • Landmark events centre, Victoria Island
  • University of Lagos, Akoka
  • MMA2 (Domestic Airport)
  • Ikeja City Mall, Alausa, Ikeja
  • Computer Village, Ikeja
Image copyright @googleafrica
Àkọlé àwòrán Igbakeji aarẹ Yẹmi Osibajọ ni ara igbesẹ ti ijọba apapọ n gbe niyi lati darapọ mọ awọn orilẹede ti o n fi imọ ẹrọ ṣọrọ

Ninu ọrọ rẹ nibẹ, igbakeji aarẹ orilẹede Naijiria, Ọjọgbọn Yẹmi Osibajọ to ṣi eto ọhun ni ara ohun to lee mu eto ẹkọ ati mọọkọ-mọọka gbẹrẹgẹjigẹ sii lagbaye ni amulo ẹrọ ayelujara.

''Loni, ida ọgọta ninu ọgọrun awọn eeyan ilẹ Afirika lo jẹ ọdọ. A ko lee tọ awọn ọdọ orilẹede yii ti iye wọn yoo ti wọ igba miliọnu ti a o ba fi de ọdun 2045 ni yara ikẹkọ kilaasi nikan"

Image copyright @googleafrica
Àkọlé àwòrán "Ko si ohun ti o ko lee fi wo, kii tan bẹẹni anfani yii yoo kan awọn agbegbe miran laipẹ"

O ni ara igbesẹ ti ijọba apapọ n gbe niyi lati darapọ mọ awọn orilẹede ti o n fi imọ ẹrọ ṣọrọ.

" Ko si ohun ti o ko lee fi wo, kii tan bẹẹni anfani yii yoo kan awọn agbegbe miran laipẹ." Ni arabinrin Juliet Ehimuan-Chiazor ti o jẹ adari ileeṣẹ Google Nigeria ṣalaye fun ikọ BBC.