Ìjàmbá afárá Ọ̀tẹ́dọlá: Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ ọlọ́kọ̀ epo tó fa ìjàmbá iná

Aworan ọkọ ajagbe akepo to n jona naa Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ilu Kano ni wọn ti mu arakunrin to ni ọkọ ajagbe akepo naa

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ọwọ awọn ti tẹ arakunrin ti o ni ọkọ agbepo to ṣokunfa ijamba ina to waye lori afara Ọtẹdọla nilu Eko.

Ninu atẹjade kan ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko fi sita, ọwọ awọn ọtọlẹmuyẹ tẹ ọgbẹni Hassan Maiwake ni ilu Kano ṣugbọn awakọ ajagbe elepo naa ṣi na papa bora.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lunar Eclipse: Ifá letùtù wa lẹyìn Òṣùpádẹ̀jẹ̀

Aworan ìṣẹlẹ òṣùpádeje káàkiri àgbáyé

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionPassport Nàìjírìa: ìjọba ti sọ gbèdéke ori ìwé ìrìnnà di ọdun mẹ́wàá

Ni ọjọ kejidinlọgbọn oṣu kẹfa ni ọkọ ajagbe elepo kan to gbe jala epo ẹgbẹrun mẹtalelọgbọn gbina lẹyin ti o ṣubu ti o si da epo silẹ kaakiri ori afara naa.

Ki ato wi, ki a to fọ, eeyan mẹsan ati ọkọ mẹrinlelaadọta lo ti jona ninu ijamba naa.

Image copyright ỌLLABỌ̀DÉ AKAMỌ
Àkọlé àwòrán Lọjọ kejidinlọgbọn oṣu kẹfa lọkọ elepo kan da ijamba ina silẹ lori afara Ọ̀tẹdọla nilu Eko to si gba ẹmi ati dukia

Gẹgẹ bii ọgbẹni Chike Oti to jẹ alukoro ileeṣẹ Ọlọpaa ipinlẹ Eko ṣe sọ, 'oju kẹrindinlogun, opopona Hitoro Limawa ni wọn ti mu arakunrin Hassan Maiwake ni ipinlẹ Kano, o si ti n ran awọn ọlọpaa lọwọ ninu iwadi wọn lati ṣawari awakọ to wa ọkọ ajagbe yii lọjọ ti iṣẹlẹ naa ṣẹ.'

O ni Ẹka ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko yoo sa gbogbo ipa rẹ lati rii daju pe awọn to padanu ẹbi ati dukia wọn sinu iṣẹlẹ naa gba idajọ ododo.