Iléeṣẹ́ aṣọ́bodè gba àgbá ọjà tó kún fún ẹrù ogun

Awọn nnkan ogun ti awọn aṣọbode gba
Àkọlé àwòrán,

opopona marosẹ Aba si Port Harcourt ni wọn ti gba ẹru ofin naa

Ileeṣẹ aṣọbode orilẹede Naijiria ti gba awọn ohun elo ologun kan ti awọn eeyan kan fẹ ko wọ orilẹede Naijiria lọna aitọ.

Ninu atẹjade kan ti alukoro ileeṣẹ naa, Joseph Attah fi sita, ileeṣẹ aṣọbode ni ọwọ awọn oṣiṣẹ ikọ ojulalakan fi nṣọri rẹ lo tẹ agba ikọja si kan ti nọmba rẹ jẹ MRSU 3040288 ti wọn fi nko ẹru nnkan ijagun naa lopopona marosẹ Aba si Port Harcourt.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Kini o wa ninu agba ikọja si naa?

  • Lẹyin ayẹwo loju aṣoju ẹni to ni i ni wọn ti ri beeli aṣọ ogun mọkanla ti ọkọọkan si ni irinwo aṣọ ogun ti wọn ti ran silẹ.
  • Paali bata tapasẹgun awọn ọmọogun marundinlogun ninu eyi ti ọkọọkan rẹ ni ogun bata yii.
  • Apo aṣọ aransilẹ
  • Aga ati ohun elo ile idana meje.
  • Ojilelọọdunrun o din mẹta paali ohun ọṣọ ilẹ iyẹn tiles oke okun ti wọn ṣe lorilẹede China.
  • Awọn ohun elo iṣegun oyinbo mẹtadinlọgbọn ti wọn ṣe lorilẹede China.
  • Ọpa ifami mẹrinlelọgbọn ti wọn ka jọ pọ soju kan lati orilẹede China.
  • Awọn ohun elo inu ile.

Ọga agba to n ṣakoso ẹka iṣẹ apapọ gbogbo fun Ẹkun kẹta, Zone C ileeṣẹ aṣọbode orilẹede Naijiria, Ahmed Azarema ni wọn ti fi aṣoju ẹni to ni awọn ọja naa si ahamọ, ti iwaadi si n tẹsiwaju lori rẹ.