#EndSARS: Oṣinbajo ní Ìjọba àpapọ̀ ti ń wáàdí àṣemáṣe ikọ̀ SARS

Yẹmi Oṣinbajo, igbkeji aarẹ orilẹede Naijiria Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Oṣinbajo ni ohun to kan awọn ikọ ọlọpaa kogberegbe SARS ni gbigbogun ti iwa idigunjale ati ijinigbe pẹlu awọn iwa ipa gbogbo miran

Ijọba apapọ ti n boju wo gulegule wahala awọn ọlọpaa kogberegbe SARS lori oniruru ẹsun aṣemaṣe ti wọn n fi kan awọn ọlọpaa ikọ naa.

Igbakeji aarẹ orilẹede Naijiria, Ọjọgbọn Yẹmi Oṣinbajo lo fi eyi to BBC leti.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Igbakeji aarẹ Oṣinbajo ni iwa awọn oṣiṣẹ ikọ naa tabi ẹnikẹni to ba n hu iwa aitọ si araalu kii ṣe ohun ti ijọba to wa lode bayii yoo fi ọwọ awẹwa mu.

O ni ohun to kan awọn ikọ ọlọpaa kogberegbe SARS ni gbigbogun ti iwa idigunjale ati ijinigbe pẹlu awọn iwa ipa gbogbo miiran sugbọn ẹsun ti awọn eeyan fi n kan wọn bayii fihan pe ibi ti wọn fi ẹlẹmọṣọ wọn ṣọ kọ lo n ṣọ bayii.

Image copyright POLICENG_PCRRU/TWITTER
Àkọlé àwòrán Iwa aṣemaṣe awọn oṣiṣẹ ikọ SARS ti di ohun ti gbogbo eeyan lorilẹede Naijiria n bu ẹnu atẹ lu bayii

Ọgọọrọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria lo si tun ti tọwọ bọ iwe ẹhonu kan ti wọn gbe ka iwaju ile aṣofin apapọ orilẹede naijiria lati pe fun wiwọgile ikọ naa, amọṣa lẹyin ọpọlọpọ oṣu, ikerora lori ikọ SARS ati aṣemaṣe wọn ko tii kuro lẹnu awọn ọmọ orilẹede Naijiria.

"Mo ti ba ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa sọrọ lori rẹ, aarẹ pẹlu nreti ẹkunrẹrẹ abọ lori awọn ohun to ti ṣẹlẹ, awọn ohun ti a ti ri nitori fidio ti o ti jade lori wọn ko kere rara."

Oṣinbajo ni bi ijọba ṣe n tiraka lati rii pe iwa ọdaran dẹkun lawujọ, o tun yẹ ka ba awọn oṣiṣẹ SARS naa sọrọ lati mọ ẹtọ awọn araalu ninu iṣẹ yoowu ti wọn ba n ṣe.