Lagbaja da ìlù bolẹ̀ nílú Abuja
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Lẹ́yín ọpọ̀lọpọ̀ ọdún, Lagbaja rèe lórí ìtàgé

Aṣe lootọ ni pe ko si bi a ti ṣe lee ṣe ebolo ti ko ni run igbẹ.

Lẹyin ọpọlọpọ ọdun ti awọn ololufẹ rẹ ti n poungbẹ fun orin rẹ, Bisade ologunde ti ọpọ mọ si Lagbaja pada de si ori itage lati da awọn eeyan laraya nilu Abuja, olu ilu Naijiria ni aṣalẹ ọjọ abamẹta.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn orin ti gbajugbaja akọrin naa fi da agbo faaji laamu lawọn ọdun diẹ sẹyin naa lo da sori igba fun awọn ololufẹ rẹ lati maa du witiwiti ti ijo si npa ijo jẹ.

Nigba ti ode ere naa yoo fi wa si idanuduro, iroyin adun rẹ ko tan lẹnu awọn to peju sibẹ, to bẹẹ gẹẹ to jẹ wi pe gbogbo ori ikanni twitter ni iroyin adun ode orin naa ti gba kan bayii.

Bakan naa, ni gbajugbaja olorin takasufe ni, Simi pẹlu wa nikalẹ ti oun naa kọrin pẹlu Lagbaja.