Ìkọlù Zamfara: Awọn kan ni 1000 agbófinró kéré, àwọn mii ni ó pọ̀jù

Aworan abule ti ikọlu ti sle ni Zamfara Image copyright STR/AFP/GETTY
Àkọlé àwòrán Ọpọ ẹmi lo ti ba isẹlẹ ipaniyan Zamfara lọ

Agbẹnusọ fún ilé iṣẹ Ààrẹ orílèèdè Naijiria Garba Sheu, tí fèsì sí ariwisi àwọn ará ìlú lórí iye agbofinro ti ìjọba fi ranṣẹ sí ipinle Zamfara, láti dẹkùn ìpeníjà àwọn jaguda agbebon.

Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹlú akoroyin BBC, Garba Shehu ní iye agbofinro tó yẹ ni ìjọba fi ranṣẹ, lẹyìn tí wọn ṣe àyẹwò ìṣẹlẹ tó n wáyé lagbegbe náà.

"Ìjọba ìbílẹ̀ kan perei ọrọ yí kan, ti a bá sì wò dáadáa a ri wí pé àwọn ọmọ ogun wá kunju oṣuwọn, láti lèe dẹkùn awọn agbebon wọn yí''

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSómólú l‘Eko: Ibùdó ìwé títẹ̀ àkọ́kọ́ ní W.Afrika

Kin ni ero awọn ọmọ Naijiria lori igbesẹ yii ?

Ṣùgbọ́n awọn ọmọ Naijirià kan ko le ro wí pé iye àwọn agbofinro yi tó lati dẹkun ipaniyan ni ipinlẹ Zamfara.

Lójú òpó Twitter àwọn kan n ṣé àfiwé iye agbofinro ti wọn ran lo sí Zamfara, pẹlú ìyè agbofinro tó lò sí ipinle Ekiti nigba ìdìbò Gómìnà ibẹ.

Onimọ eto aabo ni ‘wọn n ti-wọn n ti kọ leyin’...

Onímọ̀ nípa ètò ààbò kàn lorileede Naijiria, Tony Ofoyetan nínu ero tirẹ ni, iye ọmọ ogun tí wón rán lo sí Zamfara, paapa ti pọju.

''O dami lójú wí pé, áwọn agbegbon wọnyi ko lee to ẹgbẹrun kan ti awn ọlọpaa yii jẹ́, ẹja wọn to si n daamu ibu ko to nkan. Nitori nà, egberun kan agbofinro tó fún iṣẹ tó wà nílé yí.''

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Àarẹ Muhamadu Buhari ti se àbẹ̀wò sí ágbèègbè náà laipe yii

Tony so wi pe, bi àwọn agbofinro naa bá ṣe iṣẹ wọn bí o ti yẹ, ''kò yẹ ki o gbawọn lásìkò láti kojú awọn jaguda wọn yi''

''Ti wọn ba gbajumo isẹ otẹlẹmuye daada, ti ko si si ija laarin awọn agbofinro ti wọn ran lọ si Zamfara, o ye ki wahala yii dopin laipe.''

Image copyright ABDULRAZAQ BELLO SHARMA
Àkọlé àwòrán A gbo wi pe o to eeyan àádọ́jọ to padanu ẹmi wọn ninu ikolu yi laarin ọsẹ meji

Ninu ikọlu to waye laipe yi, awọn janduku agbebon yà lù awọn abúlé kan ni ìpínlẹ̀ Zamfara, ti wọn sì pa èèyàn mejilelogoji nigba tí wọn kọlù abúlé méjìdínlógún láwọn ìjọba ìbílẹ̀ kan nipinlẹ naa.

N se ni aworan awọn ara ilu ti wọn sa asala fun ẹmi wọn latari ikọlu naa gba ori ẹrọ ayelujara kan.

Image copyright ABDULRAZAQ BELLO SHARMA
Àkọlé àwòrán O ti to ọdun mẹjo ti awọn ara ilu Zamfara ti n koju ipenija ikọlu awọn agbebon

Lara wọn la ti ri eleyi ti awọn ara ilu to di eru wọn mọri, ti wọn si n rin pẹlu.

Lọdun yi nikan, ọgọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn ni wọn ti fara káásà ninu ìkọlù aimoye to n waye nipinlẹ Zamfara.