Omiyale Ile Ife: Dukia sọfọ, awọn eniyan si tun farapa

Àkọlé fídíò,

Omiyale Ile Ife: Dukia sọfọ, awọn eniyan si tun farapa

Awọn eniyan ti agbara ojo ni ilu Ile Ife sọ oun ti oju wọn ri lasiko omiyale to sẹlẹ laipẹ yii.

Ninu ọrọ wọn, wọn ni arọrọda ojo ni asiko ojo yii ti fa ijamba ọkọ ati wipe ọpọlọpọ eniyan lo farapa ninu isẹlẹ omiyale naa.

Awọn ara agbeegbe naa wa rọ ijọba lati ba wọn wa atunsẹ si isẹlẹ omiyale to n sẹlẹ lati igba de igba ni ile Ile-Ifẹ.

Oríṣun àwòrán, @ojedeletemitayo

Àkọlé àwòrán,

Awọn akẹkọ ileewe giga fasiti Ọbafẹmi Awolowo ni ilu Ile ifẹ naa ko ṣai fara gba ajalu naa

Awọn akẹkọ ileewe giga fasiti Ọbafẹmi Awolowo ni ilu Ile ifẹ, naa ko ṣai fara gba ajalu naa.

Ni ọdun 2017 ni irufẹ ajalu yii waye eleyi ti o sọ ọpọ di alainile.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Irú ẹ̀dá wo ni Fẹla Jẹ́?

Bi o tilẹ jẹ wi pe ijọba ti gbiyanju fifẹ oju agbara kaakiri ipinlẹ Ọṣun, ko dabi ẹni pe eyi ran wahala ikun omi ni ilu ile ifẹ.