Osun Election: Secondus sèpàdé pẹ̀lú Adeleke àtàwọn tó ń fapá-jánú

Asia ẹgbẹ́ òṣèlú People Democratic People Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn oludije kan n fapa janu lori ètò ìdìbò abẹnu PDP típínlẹ̀ Osun

Alaga apapọ̀ fẹgbẹ òṣèlú People's Democratic Party, PDP, Ọgbẹni Uche Secondus, ti dasi aawọ tó n wáyé láàrin àwọn ọmọ ẹgbẹ PDP, lori Ìdìbò abẹnu fun ipò Gómìnà to waye laipe yi nipinlẹ Osun.

Níbi ìpàdé kan tó wáyé lolu ilé ẹgbẹ náà labuja, Secondus àti àwọn ọmọ ìgbìmò amusẹya ẹgbẹ fikún-lukun pẹlú Oludije ẹgbẹ náà fún ipò Gómìnà l‘Ọ̀sun, Seneto Ademola Adeleke ati àwọn ọmọ ẹgbẹ míi ti wọn n fapa janu.

Adeleke lo jáwé olúborí nínú ìdìbò abẹnu ẹgbẹ náà, eyi tó waye losu keje odun yii, pẹlú ìbò 1,569, nigbati Akin Ogunbiyi n pọn lẹyin rẹ pẹlu ìbò 1,562.

Ṣugbọn Ogunbiyi táko èsì ìbò náà niwájú ìgbìmò apẹtu-saawọ ẹgbẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionLion Chaser: Richard, ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dógún se iná tó ń lé kìnìún

Ìròyìn tó tẹwa lọwọ sọ̀ pé, ọtọtọ ní Uche Secondus se ìpàdé pẹlú àwọn ọmọ ẹgbẹ náà àti wí pé, o ṣeéṣe kí ìgbìmò alabe-sekele kan tun ṣepàdé láti tunbo wà woroko fi ṣada lórí ọrọ náà.

Èèyàn mẹrin láti ọdọ Adeleke ati Ogunbiyi ni ìrètí wa wipe wọn yóò yan láti jo fọrọ jomitoro ọrọ lórí aawọ òhun.