Ìkọlù Plateau: Ortom ní inú òun dùn pé Buhari ń fi àmì ẹ̀yẹ dá Abdullahi lọ́lá

AworanÌmáámù Abubakar
Àkọlé àwòrán Ìmáámù Abubakar fi awọn okunrin ati obirin pamo sinu Mosalasi rẹ

Atoore ati ika, ọkan kii gbe.

Ọrọ yi se rẹgi nipa Imam ti BBC gbé ìròyìn rẹ sita lori bọ se doola ẹmi àwọn èèyàn ọ̀tàlénígba lé meji lọwọ àwọn agbebon-paniyan nipinle Plateau.

Lọ́jọ́ Ajé ni Aare Muhammadu Buhari ránṣẹ sí Imam Abubakar pé, oun fẹ ko wa bọ óun lọwọ, kí òun sì fi òye dà lọla lórí bo ti se doola ẹmi àwọn èèyàn tó sa asalà d'ọdọ rẹ, lọwọ àwọn asekupani agbebon ní àdúgbò Barkin Ladi ní ìpínlẹ̀ Plateau.

Inú mosalasi ní Abdullahi Abubakar, tó jẹ ẹni ọdún mẹtalelogun, fí àwon èèyàn naa pamọ sí lójó kẹrinlelogun osu kẹfa ọdún 2018.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionLion Chaser: Richard, ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dógún se iná tó ń lé kìnìún

Àwọn tí Abubakar doola ẹmi wọn sọ fún BBC pé, inú àwọn dùn gán bi Aare ṣe fẹ dá Abdullahi lọla.

Wọn ní bí ki ba se pe o gbe ìgbésẹ tó gbé, àwọn ki bá má wa l'ayé lóni.

Ewé, aṣojú ilé Amerika sí orílèèdè Naijirià náà ti gba lalejo.

Oju wo ni Gomina Ortom fi wo igbesẹ yii ?

Gómìnà ipinle Plateau Simon Lalong, lo fi ikede si'ta pé Ààrẹ Buhari fe fojú kan Abdullahi, níbi àpérò kan tí yóò wáyé lórí ètò alafia ati aabo.

Gómìnà Lalong ni, gbogbo ìlú ní Abdullahi dóóla ẹmi wọn pẹlú èèyàn oodunrun tí o gbà lá.

Yakubu Datti, to je agbẹnusọ fún Gómìnà Lalong ní, àìsí nílé Ààrẹ Buhari lo faa, ti àwọn kò ti le fi sọ àsìkò àti ààyè ti idanilọla náà yóò to wáyé.

Gómìnà Lalong ní, ayọ òun kún pe àsìkò ti òun jẹ Gómìnà ni irú nnkán bayii wáyé.

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí