Awọn ọlọ́pàá àti àwọn òṣiṣẹ́ ààbò ti ṣí afárá 3rd mainland padà

ọkọ̀ tó jóná
Àkọlé àwòrán ọkọ̀ wagon kan ló sàdédé gbina lori irin lórí afárá

Òpópónà afárá Third Mainland tó dí lówùrọ̀ òní kò sẹ̀yìn ìná to sẹ́yọ lára ọ̀kan lára àwọn ọkọ̀ tó ń rin lójú pópó.

Èyí ló fàá tí àwọn ọlọ́pàá fí tí apákan ọ̀nà náà, tí ìgbòkègbodò ọkọ̀ sì fi lọ́ jáí.

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn ṣe fi tó wa léti súnkẹrẹ-fàkẹrẹ ọkọ̀ láti Owonronshoki sí inú Ekó báyìí kò ṣee fẹ́nu sọ bó tile jẹ́ pé àwọn tọ́rọ̀kan ti ń sisẹ́ lée lórí.

Image copyright Empics
Àkọlé àwòrán Ọkọ̀ wagon kan ló ṣààdédé gbina lori irin lórí afárá

Ọkọ̀ epó gbina ní Banki ECO

Ìṣẹlẹ iná ọkọ agbepo kan tun ti ṣẹlẹ̀ nipinle Eko, eyi to sọ irufẹ isẹlẹ yii di kaka kewe agbọn dẹ, lile lo nle si.

Ilé epo to wa ni olu ilé iṣẹ ilé ifowopamọ Ecobank ni Victoria Island, ní ìṣẹlẹ náà ti wáyé.

Image copyright Lasema
Àkọlé àwòrán Ṣugbọn awọn panapana ti dẹkùn ina náà

Ìṣẹlẹ náà wáyé ni aaro ọjọ Isẹgun nigbati ọkọ náà n já èpo sínú akoto èpo ile ifowopamọ sí òun.

Ṣugbọn awọn panapana ti dẹkùn ina náà.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionLion Chaser: Richard, ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dógún se iná tó ń lé kìnìún

Akọroyin BBC to lọ sibi isẹlẹ naa ni, kò sí ẹni tó kù nínú ìṣẹlẹ náà ṣùgbọ́n kò ti dájú iye èèyàn to f'arapa nínú ìjàmbá ọhun.

Bákan náà ló ní, wọn ti dawọ iṣẹ dúró ní ilé ifowopamọ Eco to wa ni Victoria Island, ti wọn sì sáré ko àwọn onibara wọn jáde nínú ọọfisi wọn

Èyí ni igbákejì ti ọkọ agbepo yóò gbina nílu Èkó, lẹyìn ìṣẹlẹ tí Otedola to mú òpó ẹmi ati dukia ló.

Nigba to n sọrọ lori isẹlẹ yii ninu atẹjade kan to fi sita, ọga agba fun ajọ to n ri si akoso isẹlẹ pajawiri ni ipinl;ẹ Eko, Lasema, Adesina Tiamiyu niaago mẹjọ aabọ aarọ ọjọ isẹgun ni awn gba ipe nipa isẹlẹ naa, tawọn si dide lọgan lati lọdoola rẹ.

O ni awọn ko ti mọ ohun to fa isẹlẹ ina naa sugbọn awọn tete dide pẹ́lu ileesẹ pana-pana lati pa ina ọhun.