Bukola Saraki: Irọ́ ni pé sẹ́nétọ̀ kan yóò má gba ₦15m owó àjẹmọ́nú

Gbagede Ile Aṣofin Agba

Oríṣun àwòrán, Nigeria Senate

Àkọlé àwòrán,

Àjọ tó ń jà fún ẹ̀tọ́ àwọn ará ìlú, SERAP kéde pé Bukola Saraki ń gbìyànjú láti sọ owó àjẹmọ́nú sẹ́nétọ̀ kan da N15m.

Aarẹ Ile Igbimọ Asofin Agba, Bukọla Saraki ti ni, ko si otitọ kankan ninu ẹsun ti Ajọ to ja fun ẹtọ awọn ara ilu, SERAP kede lori afikun owo ajẹmọnu awọn sẹnetọ lorilẹede Naijiria.

Ọjọ Kẹfa, Osu Kọkanla ọdun 2018 ni Ajọ SERAP fi si ori ẹrọ ikansiraẹni Twitter rẹ pe, igbesẹ Bukola Saraki lati fikun owo ajẹmọnu awọn asofin, ti ẹni kọọkan yoo si maa gba milliọnu mẹẹdogun Naira losoosu, ko ba ofin to rọ mọ owo osu lorilẹede Naijiria mu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Grandma Maruwa: Ó yẹ kí obìnrin sisẹ́ láì wojú ọkọ kó tó jẹun

Amọ, Agbẹnusọ fun Bukola Saraki, Olu Onemola fi si ori itakun ibaraẹnisọrọ Twitter pe ẹsun ti ko lẹsẹ nlẹ ni SERAP fikan Saraki.

Onemola fikun wi pe, Ajọ SERAP to n soju awọn ọmọ Naijiria ni ko yẹ ko maa gbe iroyin ẹlẹjẹ ti gbogbo ọmọ Naijiria yoo ri sita.

Kò sí ẹni tó lè yọ Saraki - Ademọla Adeleke

Ọmọ ilé ìgbìmọ aṣòfin àgbà tó díje dupò gómìnà ìpínlẹ̀ Osun lósù tó kọja, Ademola Adeleke ní pípada síle aṣòfin lẹ́yìn tí àwọn ọmọ ile ṣe ìfọ̀rọ̀wérọ̀ ránpẹ́, kò ṣeyìn kíkẹ́dùn ọkan lára ọmọ ile igbìmọ̀ aṣojúṣofin tó papoda l'óṣù Kẹsàn án.

O fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀, lásìkò tó ń ba BBC sọ̀rọ̀ nílé ìgbìmọ aṣofin l'Abuja lónìí pé kò sí nínú ìpinu ọmọ ilé láti dìbò yọ ààrẹ ilé ìgbìmọ aṣofin.

Àkọlé fídíò,

Ademọla Adeleke: 'Àwa ò fí ti ẹgbẹ́ òṣelú ṣe nílé ìgbìmọ aṣòfin àgbà

O ní ìtẹ́síwájú orílẹ̀-èdè ló ṣe pàtàkì lásìkò yìí, àwọn kò sì fi tí ẹgbẹ́ òṣèlú ṣe rárá bíkò ṣe ọ̀nà láti wá ojúútu sí ìṣòrò tó ń ko orílẹ̀-èdè yìí lọ́wọ.

Sẹ́nàtọ́ Omo Agege: Kò tọ́ sí Saraki láti darí Ilé Asofin Agba

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK

Aarẹ Ile Igbimọ Asofin lorilẹede Naijiria, Bukola Saraki ni o dari ijoko ile loni, lẹyin ti wọn lọ fun idibo abẹlẹ ẹgbẹ oselu wọn saaju idibo gbogboogbo ti ọdun 2019.

Saraki to dari ile lo saaju awọn adari Ile Igbimọ nigba ti wọn n to lọ wọọwọ wọle pẹlu adura ni agogo mọkanla owurọ ooni lati bẹre isẹ.

Lasiko ti wọn n jiroro, Sẹnetọ Bukola Saraki ni ipade awọn toni da le lori bi Ile Igbimọ Asofin yoo se gbooro si, eyi ti yoo mu ilosiwaju ba orilẹede Naijiria lapaapọ.

Àkọlé fídíò,

'Ìlù Bàtá ló yàn mi, èmi kọ́ ni mo yàn an'

Ile Igbimo Asofin naa lọ fun isinmi lati Ọjọ Kẹrinlelogun, Ọsu Kẹjọ pada si ẹnu isẹ loni, nigbati Ile Igbimo Asojusofin yoo pejọ lati se ọfọ ọkan lara wn to papoda, Arabinrin Funke Adedoyin.

Bakan naa, Sẹnetọ to n soju ẹkun gbungun ipinlẹ Delta, Sẹnetọ Omo Agege ti kesi Bukola Saraki lati kọwe fi ipo silẹ gẹgẹbi Aarẹ Ile Igbimọ Asofin Agba.

Sẹnetọ Omo Agege ni ki alaafia o le e jọba, pe ko to si Saraki lati dari Ile Asofin Agba pẹlu bo se fi ẹgbẹ oselu APC silẹ fun PDP.

Ẹwẹ, awọn oluranlọwọ fun awọn asofin ti se ifẹhọnu han lori bi Ile Igbimọ Asofin se kọ lati san owo osu wn ati ajẹmọnu wọn.

Awọn osisẹ naa se ifẹhọnu han naa ni ayika Ile Igbimọ Asofin ni Olu-ilu orilẹede Naijiria, Abuja.

'Saraki kìí ṣe ara ìjọba wa'

Ijọba apapọ ko tii gbọ nipa ikọwe fipo silẹ aarẹ ile aṣofin agba.

Minisita feto iroyin, Lai Muhammed lo sọ bẹẹ ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC Yoruba lẹyin ti aarẹ ile aṣofin agba, Bukọla Saraki kọwe fi ipo silẹ.

Àkọlé fídíò,

Lai Mohammed: Saraki ko tíì fi ìgbésẹ̀ rẹ̀ tó wa létí

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lai Mohammed ni Sẹnetọ Saraki kii ṣe ara ijọba APC nitori naa ijọba apapọ ko lee sọ boya fifi ẹgbẹ silẹ to fi ẹgbẹ silẹ lee ni ipa kan tabi omiran.

"Awa o tii gbọ gẹgẹ bi ilana to tọ.

Inu ẹgbẹ lo ti kuro, ko kuro ni ijọba nitori kii ṣe ọmọ igbimọ ijọba wa. Ẹgbẹ ni yoo sọrọ lori boya yoo ni ipa ninu ẹgbẹ tabi rara."

Oríṣun àwòrán, Presidency Nigeria

Aarẹ ile aṣofin agba, Bukọla Saraki kede pe oun ti kuro lẹgbẹ oṣelu APC ṣugbọn ko tii sọ ibi gan ti o n doju ni pato.