Bukola Saraki - Lẹyin ọpọlọpọ ijiroro mo ti fi ẹgbẹ APC silẹ lọ PDP

Bukola Saraki

Oríṣun àwòrán, Twitter/Bukola Saraki

Àkọlé àwòrán,

Àwọn ènìyàn ti fẹ̀sì lórí ẹ̀rọ ayélujára lori iròyìn wí pé Aare ile igbimọ Asofin, Bukola Saraki ti kuro ninu ẹgbẹ oselu APC.

Aare ile igbimọ Asofin Agba, Bukola Saraki ti kuro ninu ẹgbẹ oselu APC, o si ti fi lede wipe ẹgbẹ oselu PDP ni ohun nlọ darapọ mọ.

Saraki to fi ero rẹ han lori ikanni Twitter rẹ ni wakati diẹ sẹyin, fi atẹjade sita nibi to ti fihan wi pe ẹgbẹ oselu APC ti da oun afisẹyin ti egun fi sọ, ati wipe oun ti pada si ẹgbẹ oselu PDP ti oun ti bẹrẹ irinajo oselu.

Bakannaa, Gomina ipinlẹ Kwara, Alhaji Abdulfatah Ahmed lori ikanni Twitter rẹ naa fi ipinnu rẹ han lati kuro ninu ẹgbẹ oselu APC lọ si PDP nitori ẹgbẹ oselu APC ko fun ohun laaye lati koju isoro to n koju ni ipinlẹ Kwara.

Àkọlé fídíò,

Lion Chaser: Richard, ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dógún se iná tó ń lé kìnìún

Ẹgbẹ oselu PDP, Atiku sọr lori ifẹgbẹsilẹ Saraki

Ọkan lara awọn sẹnẹto ni ile igbimo asofin agba, Ben Murray Bruce labẹ ẹgbẹ oselu PDP fi idunnu rẹ han wipe lati Saraki n bọ wa si ẹgbẹ oselu PDP, bi o tilẹ jẹ pe Saraki ko i ti fi ero rẹ han lasiko ti Bruce sọ eyi.

Lori ikannni Twitter wọn, ẹgbẹ oselu PDP ni ayo ati idunnu lo jẹ fun awọn lati ri wi pe aarẹ ile igbimọ Asofin pada si ẹgbẹ osẹlu won, ti wọn si ki ku nabo ati awọn miran bii Gomina Kwara, Ahmed Abdulfatah ati Asoju ilẹ Naijiria si South- Africa ALhaji Ahmed Ibeto pada si ẹgbẹ oselu alaburada.

Bakan naa, ninu ọrọ tirẹ, Igbakeji aarẹ tẹlẹri lorilẹede Naijiria, Atiku Abubakar sọ wi pe oun pẹlu ẹni to parwa si Saraki lati darapọ mọ PDP nitori iru iwa ti APC wusi Saraki naa ni wọn n hu si awọn ọmọ Naijiria.

Laipẹ yii ni Sẹnatọ mẹ́ẹ̀dógún fi ẹgbẹ́ òṣelú APC sílẹ̀ lọ sí PDP.