Saraki: Mo kọ́ ẹ̀kọ́ ńlá lọ́dún mẹ́ta tí mo lò ní APC

Saraki

Oríṣun àwòrán, BUKOLA SARAKI

Àkọlé àwòrán,

Saraki ni ohun ti oun fẹ ja fun labẹ aburada ẹgbẹ oṣelu PDP ni iṣọkan orilẹede Naijiria

Sẹnetọ Saraki ni ileri ayipada ọtun lo mu ki oun atawọn akẹgbẹ oun to fi PDP silẹ o darapọ ms APC.

" A kuro ni ilepa fun idajọ ododo, aisi irẹjẹ ati ibaṣepọ to dan mọran eleyi to jẹ ipinlẹ ẹgbẹ oṣelu PDP gan lati ipilẹ ki o to fi oju opo naa silẹ."

Lẹyin to darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC to si di aarẹ ile aṣofin agba labẹ ẹgbẹ oṣelu naa ni Saraki n pada si ẹgbẹ oṣelu PDP bayii, ṣugbọn ko ṣai sọ idi to n muu pada si ẹgbẹ oṣelu naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Saraki ni idi ti oun fi n pada ni pe ẹgbẹ oṣelu APC ti ṣe atunto ati atunṣe gbogbo to tọ ni ṣise.

Gẹgẹ bii Sẹnetọ Saraki ṣe sọ ninu ọrọ rẹ, lẹyin ijakulẹ rẹ ninu eto idibo apapọ to kọja nipataki julọ idibo aarẹ eleyi ti o ti fidirẹmi, o ni ẹgbẹ oṣelu PDP ti kọ ẹkọ lara ijakulẹ rẹ pẹlu agbekalẹ awọn atunṣe to yẹ.

"PDP ti a n pada si ti di ẹgbẹ oṣelu to ti kọ ẹkọ rẹ lọna to le ti wọn si ti wa mọ daju bayi pe ko si ọmọ ẹgbẹ kankan ti wọn lee yan ni pọṣin. O ti di ẹgbẹ oṣelu to ti mọ pe, koṣemani ni idajọ ododo, aisi irẹjẹ ati ibaṣepọ to dan mọran fun alaafia.

Oríṣun àwòrán, BUKOLA SARAKI

Àkọlé àwòrán,

Saraki ni idi ti oun fi n pada ni pe ẹgbẹ oṣelu APC ti ṣe atunto ati atunṣe gbogbo to tọ ni ṣise

Saraki tun tẹnu mọọ pe ẹkọ ti oun kọ laarin ọdun mẹta ti oun lo pẹlu ẹgbẹ oṣelu APC ni pe pataki julọ ojuṣe to n koju "orilẹede yii ni ọna lati mu awọn eeyan orilẹede yii ṣọkan. Ko tii si igba kan ninu itan ilẹyii ti awọn ọmọ orilẹede yii tii ta kete si orilẹede yii bii ti asiko yii."

O ni ohun ti oun fẹ ja fun labẹ aburada ẹgbẹ oṣelu PDP ni iṣọkan orilẹede Naijiria.