Buhari: Màá sisẹ́ fún ààbò àti àgbéga ẹkùn wa

Buhari ati awọn olori ijọba ni ajọ Ecowas

Oríṣun àwòrán, @BashirAhmad

Àkọlé àwòrán,

Kete ti awọn olori orilẹ-ede lẹkun iwọ oorun Afrika pari ipade ajọ Ecowas naa, ni wọn kede Buhari gẹgẹ bii alaga wọn tuntun.

Aarẹ Muhammadu Buhari ti ilẹ wa Naijiria ni ajọ to n se asepọ ni idi okoowo lẹkun iwọ oorun Afrika, ECOWAS, dibo yan gẹgẹ bii alaga rẹ nibi ipade ajọ naa to waye ni ilu Lome, tii se olu ilu orilẹ-ede Togo ni ọjọ isẹgun.

Ikede kan ti agbẹnusọ fun aarẹ Buhari, Bashir Ahmad fisita loju opo Twitter rẹ lo sisọ loju eleyii.

Oríṣun àwòrán, @BashirAhmad

Àkọlé àwòrán,

Muhammadu Buhari ni inu oun dun si bi wọn se yan oun ni alaga ajọ Ecowas

O ni ni kete ti awọn olori orilẹ-ede lẹkun iwọ oorun Afrika pari ipade ajọ Ecowas naa, ni wọn kede Buhari gẹgẹ bii alaga wọn tuntun.

Nigba to n sọ ero kan rẹ lori isẹlẹ yii, Aarẹ Muhammadu Buhari ni inu oun dun si bi wọn se yan oun ni alaga ajọ Ecowas.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Ìbaàrún pe ọdún kan

O wa jẹjẹ lati sisẹ tọkan-tara pẹlu awọn olori orilẹ-ede yoku fun ipese eto aabo to duro re, alaafia , isejọba rere ati igbaye-gbadun araalu pẹlu eto ọrọ aje to mu yan-yan, ki ẹkun iwọ oorun Afrika lee ni idagbasoke to yẹ.

Buhari wa fi ẹmi imoore rẹ han si awọn akẹẹgbẹ rẹ ninu ajọ Ecowas, ti wọn kọ lati faramọ bi oun se faake kọri lati gba ipo naa nigba ti wọn kọkọ fi ipinnu wọn ọhun to oun leti.

"Mo mọọmọ fẹ dupẹ pupọ lọwọ aarẹ orilẹ-ede Togo, Faure Gnassingbe, fun isẹ takun-takun to gbe se lasiko to n ko ajọ Ecowas sodi. mo si n fi oju sọna fun igbesẹ gbigba alejoipade ajọ Ecowas miran ni ilu Abuja losu kejila ọdun 2018."