Ìwòsàn Somalia: Pàsán àti ‘Harmala’ la fi ń se ìwòsàn òògùn olóró

Ìwòsàn Somalia: Pàsán àti ‘Harmala’ la fi ń se ìwòsàn òògùn olóró

Ileeṣẹ ọlọpa orilẹede Kenya ti yabo ibudo itọju awọn to n lo oogun oloro, ti aṣiri ifiyajẹni to n waye nibẹ tu ninu iwadi BBC Africa lọjọ isẹgun. Iwadi abẹnu ti BBC ṣafihan ilokulo to fi mọ ifiyajẹni nibudo itọju naa to wa ni ilu Nairobi, l'orilẹede Kenya.

Ọga agba kan nileeṣẹ ọlọpa fi idi rẹ mulẹ pe, lootọ ni awọn ti lọ si ibudo itọju Darushifa, ti wsn ti n tọju awọn to n lo oogun oloro. Ati pe ayẹwo ipo ti ilera awọn alaisan naa ti bẹrẹ, ti wọn si ti ni ki awọn ti ara wọn ya ,aa lọ sile wọn.

Ṣaaju ni ajọ to n mojuto awọn ibudo itọju awọn to n lo oogun oloro ni Kenya, fi iroyin sita pe ibudo ti aṣiri rẹ tu ọhun ko ni ontẹ ijọba orilẹede naa, ti wọn si tun bu ẹnu ẹtẹ lu iwa ipa ati ọdaju, ti wọn n hu si awọn alaisan naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ninu iwadi BBC African Eye nipa iwosan ni ilana ti Somalia, eyi to n waye ni ilu Nairobi, lorilẹ-ede Kenya, wọn se awari rẹ pe, awọn alfa to n lo Kurani bii oogun fun iwosan maa n lo iwa ipa fawọn oloogun oloro ti wọn n tọju.

Koda, wọn tun ri pe, oogun kan ti wọn pe ni ‘Harmala’, ti wọn maa n fun awọn eeyan naa, maa n jẹ ki wọn bì, ti wọn yoo si tun maa fi iya ajẹku-dorogbo jẹ wọn.

Awọn Alfa naa maa n gba owo ki wọn to se iwosan fun aisan, irora abi oogun oloro, ti wọn si gbagbọ pe awọn ẹni ibi lo maa n mu irora ba ẹda.

Ṣugbọn awọn to ni ibudo naa ṣẹ lori ẹsun naa.