Jiti Ogunye: Òfin ti Saraki lẹ́yìn láti máa se ààrẹ ilé lọ

Jiti Ogunye: Òfin ti Saraki lẹ́yìn láti máa se ààrẹ ilé lọ

Ọ̀pọ̀ ọmọ Nàìjíríà ló ti ń sọ èrò wọn han lóri ìgbésẹ̀ ààrẹ ilé ìgbìmọ̀ aṣofin agba, Bukola Saraki, lati fi ẹgbẹ́ òṣèlú APC silẹ.

Bukọla Saraki sọ pé òun kúro nínú ẹgbẹ́ APC, nitori gbogbo ènìyàn ti mọ pé inu ẹgbẹ oselu People's Democratic Party ,PDP, ni ọkan oun wà.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Jiti Ogunye, tó bá BBC sọrọ̀ sàlàyé pé òfin Nàìjíríà tí fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, òmìmi kan-kan kò lee mi ipò rẹ̀ nílé ìgbìmọ asòfin agba níwọn ìgbá ti ọmọ ilé tó pọ̀ jùlọ bá ti wà lẹyin rẹ̀.